Sáàmù 98:1-9

  • Jèhófà jẹ́ Olùgbàlà àti Onídàájọ́ òdodo

    • Jèhófà jẹ́ kí a mọ ìgbàlà rẹ̀ (2, 3)

Orin. 98  Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+Nítorí ó ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+ Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àní apá mímọ́ rẹ̀, ti mú ìgbàlà wá.*+   Jèhófà ti jẹ́ kí á mọ ìgbàlà rẹ̀;+Ó ti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè rí òdodo rẹ̀.+   Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sí ilé Ísírẹ́lì.+ Gbogbo ayé ti rí ìgbàlà* Ọlọ́run wa.+   Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ayé. Ẹ túra ká, ẹ kígbe ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.*+   Ẹ fi háàpù kọ orin ìyìn* sí Jèhófà,Àní háàpù àti orin tó dùn.   Pẹ̀lú kàkàkí àti ìró ìwo,+Ẹ kígbe ìṣẹ́gun níwájú Ọba náà, Jèhófà.   Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá,Ayé* àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.   Kí àwọn odò pàtẹ́wọ́;Kí àwọn òkè kígbe ayọ̀ pa pọ̀+   Níwájú Jèhófà, nítorí ó ń bọ̀ wá* ṣe ìdájọ́ ayé. Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,*+Yóò sì dá ẹjọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí ó tọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ti jẹ́ kó ṣẹ́gun.”
Tàbí “ìṣẹ́gun.”
Tàbí “kọrin.”
Tàbí “kọrin.”
Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
Tàbí “ó ti dé láti.”
Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”