Sáàmù 23:1-6

  • “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi”

    • “Èmi kì yóò ṣaláìní” (1)

    • “Ó tù mí lára” (3)

    • “Ife mi kún dáadáa” (5)

Orin Dáfídì. 23  Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.+ Èmi kì yóò ṣaláìní.+  2  Ó mú mi dùbúlẹ̀ ní ibi ìjẹko tútù;Ó darí mi sí àwọn ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.*+  3  Ó tù mí* lára.+ Ó darí mi ní ipa ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.+  4  Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,+Mi ò bẹ̀rù ewukéwu,+Nítorí o wà pẹ̀lú mi;+Ọ̀gọ* rẹ àti ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.*  5  O tẹ́ tábìlì fún mi níwájú àwọn ọ̀tá mi.+ O fi òróró pa orí mi;*+Ife mi kún dáadáa.+  6  Dájúdájú, ire àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+Èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí kó jẹ́, “síbi omi tó pa rọ́rọ́.”
^ Tàbí “Ó tu ọkàn mi.”
^ Tàbí “ń tù mí nínú.”
^ Ìyẹn, ọ̀pá tí orí rẹ̀ rí rubutu.
^ Tàbí “tu orí mi lára.”