Sáàmù 67:1-7
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin atunilára. Orin.
67 Ọlọ́run yóò ṣojú rere sí wa, yóò sì bù kún wa;Yóò mú kí ojú rẹ̀ tàn sí wa lára+ (Sélà)
2 Kí àwọn èèyàn lè mọ ọ̀nà rẹ ní gbogbo ayé+Àti àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè.+
3 Kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, Ọlọ́run;Kí gbogbo àwọn èèyàn máa yìn ọ́.
4 Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè máa dùn, kí wọ́n sì máa kígbe ayọ̀,+Nítorí wàá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó tọ́.+
Wàá ṣamọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè ayé. (Sélà)
5 Kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, Ọlọ́run;Kí gbogbo àwọn èèyàn máa yìn ọ́.
6 Ilẹ̀ yóò mú èso jáde;+Ọlọ́run, àní Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.+
7 Ọlọ́run yóò bù kún wa,Gbogbo ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “bọlá fún un.”

