Sáàmù 29:1-11
Orin Dáfídì.
29 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ọmọ àwọn alágbára,Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+
2 Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.
Ẹ forí balẹ̀ fún* Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́.*
3 A gbọ́ ohùn Jèhófà lórí omi;Ọlọ́run ológo sán ààrá.+
Jèhófà wà lórí omi púpọ̀.+
4 Ohùn Jèhófà ní agbára;+Ohùn Jèhófà ní ọlá ńlá.
5 Ohùn Jèhófà ń fa àwọn igi kédárì ya;Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń fa àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì+ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
6 Ó ń mú kí Lẹ́bánónì* máa ta pọ́n-ún pọ́n-ún bí ọmọ màlúùÀti Síríónì+ bí akọ ọmọ màlúù igbó.
7 Ohùn Jèhófà ń mú kí mànàmáná kọ;+
8 Ohùn Jèhófà ń mú kí aginjù mì tìtì;+Jèhófà ń mú kí aginjù Kádéṣì+ mì tìtì.
9 Ohùn Jèhófà kó jìnnìjìnnì bá àwọn àgbọ̀nrín, wọ́n sì bímọ,Bákan náà, ó ń tú àwọn igbó kìjikìji sí borokoto.+
Gbogbo àwọn tó wà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ sì sọ pé: “Ògo!”
10 Jèhófà gúnwà sórí ìkún omi;*+Jèhófà gúnwà bí Ọba títí láé.+
11 Jèhófà yóò fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní agbára.+
Jèhófà yóò fi àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀.+

