Sáàmù 130:1-8

  • “Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́”

    • ‘Tó bá jẹ́ àṣìṣe lo fẹ́ máa wò’ (3)

    • Ìdáríjì tòótọ́ wà lọ́dọ̀ Jèhófà (4)

    • “Mò ń retí Jèhófà” (6)

Orin Ìgòkè. 130  Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́, Jèhófà.+  Jèhófà, gbọ́ ohùn mi. Kí etí rẹ ṣí sí ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.  Jáà,* tó bá jẹ́ pé àṣìṣe lò ń wò,*Jèhófà, ta ló lè dúró?+  Nítorí ìdáríjì tòótọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ,+Kí a lè máa bọ̀wọ̀ fún ọ.*+  Mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, gbogbo ara* mi gbẹ́kẹ̀ lé e;Mò ń dúró de ọ̀rọ̀ rẹ̀.  Mò* ń retí Jèhófà,+Ju bí àwọn olùṣọ́ ṣe ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́,+Àní, ju bí àwọn olùṣọ́ ṣe ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.  Kí Ísírẹ́lì máa dúró de Jèhófà,Nítorí ìfẹ́ Jèhófà kì í yẹ̀,+Ó sì ní agbára ńlá tó lè fi rani pa dà.  Yóò ra Ísírẹ́lì pa dà nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “ṣọ́.”
Ní Héb., “bẹ̀rù rẹ.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Ọkàn mi.”