Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

B1

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Jèhófà Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ló dára jù lọ. Ohun tó ní lọ́kàn fún ayé yìí àti aráyé máa ṣẹ.

Lẹ́yìn 4026 Ṣ.S.K.

Ohun tí “ejò” náà ń sọ ni pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso kò dára. Jèhófà ṣèlérí pé òun á gbé “ọmọ,” tàbí “èso” kan dìde tó máa tẹ ejò yẹn, ìyẹn Sátánì, rẹ́ níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5,15, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Àmọ́, Jèhófà fàyè gba àwọn èèyàn láti máa ṣàkóso ara wọn bí ejò náà ṣe ń darí wọn.

1943 Ṣ.S.K.

Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé “ọmọ” tí òun ṣèlérí náà yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Lẹ́yìn 1070 Ṣ.S.K.

Jèhófà mú un dá Ọba Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ lójú pé “ọmọ” tí òun ṣèlérí náà yóò wá láti ìlà ìdílé wọn.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 16; 1 Àwọn Ọba 9:3-5; Àìsáyà 9:6, 7.

29 S.K.

Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni “ọmọ” tí òun ṣèlérí tó jẹ́ Ajogún ìtẹ́ Dáfídì.—Gálátíà 3:16; Lúùkù 1:31-33; 3:21, 22.

33 S.K.

Ejò náà, ìyẹn Sátánì dí “ọmọ” ìlérí náà lọ́wọ́ nígbà tó pa Jésù. Jèhófà gbé Jésù dìde sí ìyè ti ọ̀run, ó sì tẹ́wọ́ gba ìtóye ìwàláàyè pípé tí Jésù fi rúbọ, ó tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà kí Ọlọ́run sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣe 2:32-36; 1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.

Nǹkan Bíi 1914 S.K.

Jésù ju ejò náà, Sátánì sí ayé, ó sì sé e mọ́ ibẹ̀ fún àkókò kúkúrú.—Ìfihàn 12:7-9, 12.

Ọjọ́ Iwájú

Ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni Jésù á fi ti Sátánì mọ́ ẹ̀wọ̀n, lẹ́yìn náà ó máa pa á run, tó túmọ̀ sí pé á fọ́ ọ lórí. Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún ayé yìí àti aráyé máa ṣẹ, á mú gbogbo ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀, á sì dá ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso láre.—Ìfihàn 20:1-3, 10; 21:3, 4.