Sáàmù 76:1-12

  • Ọlọ́run ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Síónì

    • Ọlọ́run ń gba àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ là (9)

    • Ọlọ́run máa rẹ àwọn agbéraga ọ̀tá wálẹ̀ (12)

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.+ Orin Ásáfù. Orin. 76  A mọ Ọlọ́run ní Júdà;+Orúkọ rẹ̀ tóbi ní Ísírẹ́lì.+   Àgọ́ rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù,+Ibùgbé rẹ̀ sì wà ní Síónì.+   Ibẹ̀ ló ti ṣẹ́ àwọn ọfà oníná tó jáde látinú ọrun,Títí kan apata àti idà pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ogun míì.+ (Sélà)   Ìwọ ń tàn yanran;*O ní ọlá ńlá ju àwọn òkè tó ní àwọn ẹran.   Wọ́n ti kó ẹrù àwọn tó nígboyà. Oorun ti gbé wọn lọ;+Gbogbo àwọn jagunjagun ò lè ṣe nǹkan kan.+   Ọlọ́run Jékọ́bù, nípa ìbáwí rẹ,Ẹṣin àti ẹni tó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti sùn lọ fọnfọn.+   Ìwọ nìkan ló yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù.+ Ta ló lè dúró níwájú ìbínú gbígbóná rẹ?+   O kéde ìdájọ́ láti ọ̀run;+Ẹ̀rù ba ayé, ó sì dákẹ́+   Nígbà tí Ọlọ́run dìde láti mú ìdájọ́ ṣẹ,Láti gba gbogbo àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ayé là.+ (Sélà) 10  Nítorí pé ìrunú èèyàn yóò yọrí sí ìyìn rẹ;+Èyí tó kù lára ìrunú wọn ni ìwọ yóò fi ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. 11  Ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì san án,+Kí gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ mú ẹ̀bùn wọn wá pẹ̀lú ìbẹ̀rù.+ 12  Yóò rẹ ògo* àwọn aṣáájú wálẹ̀;Ó ń mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ìmọ́lẹ̀ bò ọ́ pátápátá.”
Ní Héb., “ẹ̀mí.”