Sáàmù 22:1-31

  • Ẹni tí kò nírètí wá dẹni tó ń ṣọpẹ́

    • “Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” (1)

    • ‘Wọ́n ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi’ (18)

    • Yin Ọlọ́run láàárín ìjọ (22, 25)

    • Gbogbo ayé yóò máa jọ́sìn Ọlọ́run (27)

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Egbin Àfẹ̀mọ́jú.”* Orin Dáfídì. 22  Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?+ Kí nìdí tí o fi jìnnà sí mi láti gbà mí sílẹ̀,Tí o sì jìnnà sí igbe ìrora mi?+   Ọlọ́run mi, mò ń ké pè ọ́ ní ọ̀sán, àmọ́ o ò dáhùn;+Kódà ní òru, mi ò dákẹ́.   Àmọ́ ẹni mímọ́+ ni ọ́,Ìyìn Ísírẹ́lì sì yí ọ ká.*   Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀ lé;+Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ, o sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.+   Ìwọ ni wọ́n ké pè, o sì gbà wọ́n;Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ, o ò sì já wọn kulẹ̀.*+   Àmọ́ kòkòrò mùkúlú ni mí, èmi kì í ṣe èèyàn,Àwọn èèyàn ń fi mí ṣẹ̀sín,* aráyé ò sì kà mí sí.+   Gbogbo àwọn tó ń rí mi ló ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;+Wọ́n ń yínmú, wọ́n sì ń mi orí wọn, pé:+   “Ó fi ara rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. Kí Ó gbà á sílẹ̀ báyìí! Kí Ó gbà á là, ṣebí ó fẹ́ràn Rẹ̀ gan-an!”+   Ìwọ ni Ó gbé mi jáde láti inú ìyá mi,+Ìwọ ni O mú kí ọkàn mi balẹ̀ ní àyà ìyá mi. 10  Ọwọ́ rẹ ni mo wà* látìgbà tí wọ́n ti bí mi;Ìwọ ni Ọlọ́run mi láti inú ìyá mi wá. 11  Má jìnnà sí mi, torí wàhálà ti dé tán+Mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́+ míì. 12  Ọ̀pọ̀ akọ ọmọ màlúù yí mi ká;+Àwọn akọ màlúù Báṣánì tó lágbára rọ̀gbà yí mi ká.+ 13  Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi,+Bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, tó sì ń fa ẹran ya.+ 14  A tú mi jáde bí omi;Gbogbo egungun mi ti yẹ̀. Ọkàn mi ti dà bí ìda;+Ó yọ́ nínú mi lọ́hùn-ún.+ 15  Okun mi ti tán, mo dà bí èéfọ́ ìkòkò;+Ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ ẹran ìdí eyín mi;+O sì mú mi wálẹ̀ sínú ekuru kí n lè kú.+ 16  Nítorí àwọn ajá yí mi ká;+Wọ́n ká mi mọ́ bí ìgbà tí àwọn aṣebi bá káni mọ́,+Wọ́n wà níbi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi bíi kìnnìún.+ 17  Mo lè ka gbogbo egungun mi.+ Wọ́n ń wò mí, wọ́n sì tẹjú mọ́ mi. 18  Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn,Wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.+ 19  Àmọ́ ìwọ, Jèhófà, má jìnnà sí mi.+ Ìwọ ni okun mi; tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+ 20  Gbà mí* lọ́wọ́ idà,Gba ẹ̀mí mi tó ṣeyebíye* lọ́wọ́ èékánná* ajá;+  21  Gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún  + àti lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù igbó;Dá mi lóhùn, kí o sì gbà mí sílẹ̀. 22  Màá sọ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi;+Màá sì yìn ọ́ láàárín ìjọ.+ 23  Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ọmọ* Jékọ́bù, ẹ yìn ín lógo!+ Ẹ máa bẹ̀rù rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ* Ísírẹ́lì. 24  Nítorí kò gbójú fo ìyà tó ń jẹ ẹni tí ara ń ni, kò sì ṣàìka ìpọ́njú rẹ̀ sí;+Kò gbé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún un.+ Nígbà tó ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́.+ 25  Màá yìn ọ́ láàárín ìjọ ńlá;+Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi níwájú àwọn tó bẹ̀rù rẹ. 26  Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ á jẹ, wọ́n á sì yó;+Àwọn tó ń wá Jèhófà yóò yìn ín.+ Kí wọ́n gbádùn ayé* títí láé. 27  Gbogbo ayé á rántí, wọ́n á sì yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà. Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè á tẹrí ba níwájú rẹ.+ 28  Nítorí pé ti Jèhófà ni ìjọba;+Ó ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè. 29  Gbogbo àwọn tó láásìkí* nínú ayé á jẹ, wọ́n á sì tẹrí ba;Gbogbo àwọn tó ń lọ sínú erùpẹ̀ yóò wólẹ̀ níwájú rẹ̀;Kò sí ìkankan lára wọn tó lè dá ẹ̀mí* rẹ̀ sí. 30  Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn* yóò máa sìn ín;Ìran tó ń bọ̀ yóò gbọ́ nípa Jèhófà. 31  Wọ́n á wá, wọ́n á sì sọ nípa òdodo rẹ̀. Wọ́n á sọ fún àwọn ọmọ tí a máa bí nípa ohun tó ṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohùn orin tàbí oríṣi orin kan.
Tàbí “O gúnwà láàárín (lórí) ìyìn Ísírẹ́lì.”
Tàbí “dójú tì wọ́n.”
Tàbí “Ẹni ẹ̀gàn ni mí lójú àwọn èèyàn.”
Ní Héb., “ni wọ́n jù mí sí.”
Tàbí “Gba ọkàn mi.”
Ní Héb., “ọ̀kan ṣoṣo mi,” ó ń tọ́ka sí ọkàn tàbí ẹ̀mí rẹ̀.
Ní Héb., “ọwọ́.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “Kí ọkàn yín wà.”
Ní Héb., “àwọn tó sanra.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Èso kan.”