Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

‘Ẹ MÁA WÁ ÀLÀÁFÍÀ’!

Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2022

A fẹ́ kó o wo àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ṣe lọ́dún yìí

Torí àrùn Corona, a máa gbé fídíò àpéjọ yìí sórí jw.org. Àá máa gbé apá kọ̀ọ̀kan sórí ìkànnì náà díẹ̀díẹ̀ lóṣù July àti August.

Ọ̀fẹ́ ni ètò yìí. Ibi tí gbogbo èèyàn á ti lè rí i wò láìforúkọ sílẹ̀ la máa gbé e sí.

Àwọn Nǹkan Tá A Máa Gbádùn

Ètò Friday: Wàá rí bí ìfẹ́ ṣe lè mú kí ọkàn wa balẹ̀, kí àlàáfíà sì wà láàárín àwa àtàwọn míì. Wàá tún rí ìdí tí Bíbélì fi dà bí ìwé atọ́nà tó sọ ohun táwọn tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè ṣe kí àlàáfíà lè wà nínú ìdílé.

Ètò Saturday: Ṣé ó ṣeé ṣe kí ọkàn èèyàn balẹ̀ tó bá ń ṣàìsàn, tí ò lówó lọ́wọ́, tí àjálù ṣẹlẹ̀ lágbègbè ẹ̀ tàbí tó ń kojú àwọn ìṣòro míì? A máa wo fídíò kan tó máa jẹ́ ká rí ohun táwọn èèyàn kárí ayé ń ṣe kí ọkàn wọn lè balẹ̀ láìka ohun tí wọ́n ń dojú kọ.

Ètò Sunday: Ṣé àwa èèyàn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Ṣé a lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run láìṣe ohunkóhun, àbí ohun kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀? Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn nínú àsọyé Bíbélì kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Báwo Lo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?”

Wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa ohun tá a máa gbádùn ní àpéjọ yìí àti fídíò tó ṣàlàyé báwọn àpéjọ wa ṣe máa ń rí.

 
Wo Àpéjọ Agbègbè