Ìrànlọ́wọ́ Lórí Ìkànnì

Bó O Ṣe Lè Lo JW.ORG

Kọ́ bó o ṣe lè lo àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì jw.org. Lo àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó rọrùn àtàwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lọ káàkiri lórí ìkànnì náà, láti wá nǹkan tàbí wa nǹkan jáde. Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ìkànnì jw.org.

Tẹlifíṣọ̀n JW

A lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lo Ètò Tẹlifíṣọ̀n àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ìkànnì tv.jw.org. Mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè wo ètò tó ń lọ lọ́wọ́, bó o ṣe lè wo fídíò lóríṣiríṣi àtàwọn nǹkan míì.

JW Library

Ka Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. Máa fi wé ohun tó wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì.

JW Library Sign Language

Fi ètò ìṣiṣẹ́ tá a ṣe wa fídíò Bíbélì àtàwọn ìwé míì jáde lédè adití, kó o sì máa wò ó.

Watchtower Library

Àkójọ oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì, ìwé ńlá àtàwọn ohun tó o lè fi ṣèwádìí tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

JW Language

Ètò ìṣiṣẹ́ tá a fi ń kọ́ èdè yìí ní àwọn ohun tá a lè sọ lóde ìwàásù lóríṣiríṣi èdè. Ó ní àwọn káàdì téèyàn fi ń kọ́ èdè, ọ̀rọ̀ tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀, a fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ àwọn èdè tí álífábẹ́ẹ̀tì wọn yàtọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.