Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹlifíṣọ̀n JW Lórí Amazon Fire TV

Tẹlifíṣọ̀n JW Lórí Amazon Fire TV

Tọmọdé-tàgbà ló lè gbádùn Tẹlifíṣọ̀n JW, àwọn ètò orí rẹ̀ sì lè mú kéèyàn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Wo àwọn fídíò tá à ń gbé jáde látinú yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ wa, tó fi mọ́ àwọn fídíò kan látorí ìkànnì jw.org. Lọ sí Ètò Tó Ń Lọ Lọ́wọ́ kó o lè wo irú àwọn fídíò yẹn, ì báà jẹ́ ọ̀sán àbí òru, tàbí kó o wá àwọn fídíò tó o lè wò lábẹ́ ìsọ̀rí Wo Fídíò Lóríṣiríṣi. Lọ sí Àtẹ́tísí kó o lè tẹ́tí sí oríṣiríṣi ètò, títí kan orin, àwòkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà bí ẹni ṣeré ìtàn.

Tó o bá fẹ́ wò ó lórí ìkànnì látorí kọ̀ǹpútà, tablet àbí fóònù, lọ́ sí tv.jw.org. Tó o bá fẹ́ wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n, lo Amazon Fire TV, Apple TV àbíRoku digital media player.

 

NÍ APÁ YÌÍ

Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Amazon Fire TV

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè ṣètò Amazon Fire TV rẹ, kó o sì wo Tẹlifíṣọ̀n JW lórí ẹ̀.

Wo fídíò lóríṣiríṣi lórí Amazon Fire TV

Wá fídíò, ṣe fídíò bó o ṣe fẹ́, kó o sì wo àwọn fídíò tó wà tàbí èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé.

Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀ Lórí Amazon Fire TV

Tẹ́tí sí ọ̀kan lára ohùn tá a gbà sílẹ̀ tàbí gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí kan. Ṣe àtẹ́tísí bó o ṣe fẹ́.

Bó O Ṣe Lè Wá Àtẹ́tísí àti Fídíò Lórí Amazon Fire TV

Bó o ṣe lè tètè wá fídíò, orin tàbí àwọn àtẹ́tísí míì ní apá tá a pè ní Wá a.

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—Tẹlifíṣọ̀n JW (Lórí Fire TV)

Wo ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè.