Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸLIFÍṢÒN JW

Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Amazon Fire TV

Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Amazon Fire TV

Kó o tó lè wo Tẹlifíṣọ̀n JW lórí Amazon Fire TV, àfi kó o kọ́kọ́ ṣètò ẹ̀, kó o sì fi ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW sórí Fire TV rẹ. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè bẹ̀rẹ̀:

 Set Up Your Amazon Fire TV

Ìtọ́ni máa bá Amazon Fire TV rẹ wá kó o lè ṣètò ẹ̀, kó o sì lè lò ó lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí Amazon Fire TV rẹ bá ti wọ orí íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹ̀ lé ìtọní tó bá gbé wá sójú tẹlifíṣọ̀n ẹ kó o lè parí iṣẹ́ lórí ẹ̀. Ó lè ní kó o wọlé sórí àkáǹtì Amazon rẹ kó o tó lè lo Amazon Fire TV rẹ.

Àkíyèsí: Àfi kó o lo íńtánẹ́ẹ̀tì látorí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù kan kó o tó lè parí iṣẹ́ lórí Fire TV rẹ.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò tó ṣàlàyé bó o ṣe lè ṣe é.

 Fi Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Amazon Fire TV

Lọ síbi ìbẹ̀rẹ̀ Amazon Fire TV, kó o wá tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí kó o lè fi Tẹlifíṣọ̀n JW sórí ẹ̀:

  • Tẹ Up tàbí Down lórí rìmóòtù Amazon Fire TV rẹ tó fi máa gbé atọ́ka sórí Search.

  • Tẹ Select.

Àpótí Search tó wà lórí Fire TV máa ń rí àwọn fíìmù, ètò tẹlifíṣọ̀n, àwọn òṣèré, olùdarí fíìmù, ètò ìṣiṣẹ́, àwọn géèmù àtàwọn ètò tó bá ohun tó o tẹ̀ mu. Wá JW Broadcasting nínú èsì tó jẹ mọ́ Enter Apps & Games. Tẹ ọ̀rọ̀ náà jw broadcasting.

Tó bá ti gbé e wá nínú èsì, tẹ Down kó o lè gbé atọ́ka rìmóòtù sórí JW Broadcasting níbi àwọn èsì yẹn, kó o wá tẹ Select. Tẹ Right títí atọ́ka fi máa dé orí ètò ìṣiṣẹ́ náà, kó o wá tẹ Select. Tẹ Get kó o lè wà á jáde sórí Amazon Fire TV rẹ. Tó o bá ti wà á jáde tán, bọ́tìnì Get yẹn máa yí pa dà di Open.

Kó o lè wo Tẹlifíṣọ̀n JW, tẹ Open, tàbí kó o pa dà sí ìbẹ̀rẹ̀ Amazon Fire TV kó o wá lọ wá a níbi Apps. Wo apá Your Apps Library.