Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸLIFÍṢỌ̀N JW

Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀ Lórí Apple TV

Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀ Lórí Apple TV

Ní ìsọ̀rí Àtẹ́tísí wàá rí oríṣiríṣi àtẹ́tísí, bí orin, àwòkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà bí ẹni ń ṣeré ìtàn.

(Àkíyèsí: Rìmóòtù Siri tìẹ lè yàtọ̀ sí tinú àwòrán tó wà ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.)

Yan Àtẹ́tísí níbi ìbẹ̀rẹ̀ Tẹlifíṣọ̀n JW kó o lè rí gbogbo àtẹ́tísí tó wà. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè wá àwọn àtẹ́tísí, kó o sì gbọ́ wọn:

 Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀

Ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá rí àwọn àtẹ́tísí tá a kó jọ sábẹ́ ìsọ̀rí kan. O máa rí orúkọ ìsọ̀rí náà lọ́wọ́ òkè.

 • Fìka fa ojú rìmóòtù rẹ lọ sí apá Òkè tàbí Ìsàlẹ̀ kó o lè lọ sí ìsọ̀rí tó wù ẹ́.

 • Fìka fa ojú rìmóòtù rẹ lọ sí apá Òsì tàbí Ọ̀tún kó o lè lọ sórí èyí tó o fẹ́ lábẹ́ ìsọ̀rí kan. Àwòrán èyí tó o bá gbé atọ́ka rìmóòtù sí máa tóbi díẹ̀ ju àwọn yòókù lọ.

 • Tẹ oju rìmóòtù náà kó o lè yan ìsọ̀rí tí atọ́ka wà, kó o sì lè rí Audio Program Details.

Yan ọ̀kan nínú àwọn àbá yìí:

 • Gbádùn Ẹ̀: Àtẹ́tísí náà máa bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀.

 • Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí ètò tó wà lójú tẹlifíṣọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́. Tó o bá ti gbádùn gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn tán, ó máa dáwọ́ dúró.

 • Pa Dà Bẹ̀rẹ̀: Ó máa pa dà bẹ̀rẹ̀ àtẹ́tísí náà níbi tó o gbọ́ ọ dé.

Ọ̀wọ́ àwọn àtẹ́tísí tó wà nísàlẹ̀ Audio Program Details ni àwọn àtẹ́tísí míì tó wà ní ìsọ̀rí yẹn. Tẹ Down kó o lè lọ síbẹ̀, tẹ Up kó o lè pa dà síbi Audio Program Details.

 Tẹ́tí sí Àwọn Èyí Tó Wà Lábẹ́ Ìsọ̀rí Kan

Yàtọ̀ sí pé kó o gbọ́ àwọn àtẹ́tísí níkọ̀ọ̀kan, o tún lè tẹ́tí sí gbogbo èyí tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan. Lábẹ́ Àtẹ́tísí, lọ síbi ìsọ̀rí tó o fẹ́ tẹ́tí sí, kó o wá yan ọ̀kan nínú àwọn àbá yìí:

 • Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́.

 • Lọ́kan-ò-jọ̀kan: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn láìtò ó tẹ̀ léra bó ṣe wà lójú tẹlifíṣọ̀n.

Tó o bá ti gbádùn gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn tán, ó máa dáwọ́ dúró.

 Ṣe Àtẹ́tísí Bó O Ṣe Fẹ́

Tí àtẹ́tísí bá ń lọ lọ́wọ́, o lè fi rìmóòtù Siri rẹ ṣe é bó o ṣe fẹ́:

 • Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná: Wàá lè dá àtẹ́tísí dúró. Tó o bá tún tẹ bọ́tìnì yẹn kan náà, ó máa bẹ̀rẹ̀ pa dà. O tún lè tẹ ibi tó sún mọ́ àárín lójú rìmóòtù ẹ kó o lè dá àtẹ́tísí náà dúró àbí kó o máa wò ó lọ.

 • Tó o bá ti dá àtẹ́tísí dúró, fìka fa ojú rìmóòtù sí apá Òsì kó lè pa dà sọ́wọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àtẹ́tísí náà. Tẹ Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná kó o lè máa wò ó lọ.

 • Lọ Síwájú: Tó o bá ti dá àtẹ́tísí dúró, fìka fa ojú rìmóòtù sí apá Ọ̀tún kó lè lọ sọ́wọ́ ìparí àtẹ́tísí náà. Tẹ Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná kó o lè máa wò ó lọ.

 • Sún Un Síwájú: Tó o bá fẹ́ kí àtẹ́tísí fi ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá lọ síwájú, fìka tẹ apá ọ̀tún ojú rìmóòtù.

 • Tó o bá ti rí àmì Skip níbi tó o gbọ́ àtẹ́tísí náà dé nísàlẹ̀ ojú tẹlifíṣọ̀n, tẹ ojú rìmóòtù náà.

 • Sún Un Sẹ́yìn: Tó o bá fẹ́ kí fídíò fi ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá lọ sẹ́yìn, fìka tẹ apá òsì ojú rìmóòtù mọ́lẹ̀.

 • Tó o bá ti rí àmì Skip níbi tó o gbọ́ àtẹ́tísí náà dé nísàlẹ̀ ojú tẹlifíṣọ̀n, tẹ ojú rìmóòtù náà.

 • Menu: Pa dà sí Audio Program Details.