TẸLIFÍṢỌ̀N JW
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè—Tẹlifíṣọ̀n JW (Lórí Fire TV)
Ọ̀rọ̀ tó o fi ń wà lè má tọ̀nà. (Wo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a pè ní Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Amazon Fire TV.) Tàbí kó jẹ́ pé tẹlifíṣọ̀n ẹ ò bá a ṣiṣẹ́. Amazon Fire TV and Amazon Fire TV Stick ló ń bá Tẹlifíṣọ̀n JW ṣiṣẹ́.
Tẹlifíṣọ̀n JW ń bá Amazon Fire TV àti Amazon Fire TV Stick ṣiṣẹ́.
Wo àwọn èdè tó wà lórí Amazon Fire TV. Tó o bá fẹ́ yí èdè pa dà, lọ sí Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá tẹ Select a Language.
Ọ̀fẹ́ ni tó o bá fẹ́ wa ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW jáde kó o sì máa lò ó.
Ó ṣe pàtàkì kó o yan ọ̀nà tó o fẹ́ gbà máa sanwó lórí àkáǹtì rẹ ní Amazon kó o lè máa rí ètò ìṣiṣẹ́ rà lórí ìkànnì wọn. Tó o bá fẹ́ máa wa ètò ìṣiṣẹ́ jáde lọ́fẹ̀ẹ́ láìyan ọ̀nà tí wàá máa gbà sanwó, lọ sí abala Amazon’s Help & Customer Service.
Ọ̀rẹ́ rẹ tó mọ̀ nípa Amazon Fire TV tàbí Tẹlifíṣọ̀n JW lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ìbéèrè ẹ bá jẹ mọ́ Amazon Fire TV tó ò ń lò tàbí àkáǹtì tó o ní lórí ìkànnì, lọ sí abala ìrànlọ́wọ́ lórí ìkànnì Amazon. Tó o bá níṣòro pẹ̀lú ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW, jọ̀ọ́, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó sún mọ́ ẹ jù.

