Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸLIFÍṢÒN JW

Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀ Lórí Amazon Fire TV

Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀ Lórí Amazon Fire TV

Ní ìsọ̀rí Àtẹ́tísí wàá rí oríṣiríṣi àtẹ́tísí, bí orin, àwòkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà bí ẹni ń ṣeré ìtàn.

(Àkíyèsí: Rìmóòtù Siri tìẹ lè yàtọ̀ sí tinú àwòrán tó wà ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.)

Yan Àtẹ́tísí níbi ìbẹ̀rẹ̀ kó o lè rí gbogbo àtẹ́tísí tó wà. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè wá àwọn àtẹ́tísí, kó o sì gbọ́ wọn

 Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀

Ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá rí àwọn àtẹ́tísí tá a kó jọ sábẹ́ ìsọ̀rí kan. O máa rí orúkọ ìsọ̀rí náà lọ́wọ́ òkè.

 • Up àti Down: Lọ sí ìsọ̀rí tó wù ẹ́.

 • Left àti Right: Lọ sórí èyí tó o fẹ́ lábẹ́ ìsọ̀rí kan.

Tẹ Select kó o lè yan èyí tí atọ́ka rìmóòtù wà, kó o sì rí Audio Program Details.

Yan ọ̀kan nínú àwọn àbá yìí:

 • Gbádùn Ẹ̀: Àtẹ́tísí náà máa bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀.

 • Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí ètò tó wà lójú tẹlifíṣọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́. Tó o bá ti gbádùn gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn tán, ó máa dáwọ́ dúró.

 • Pa Dà Bẹ̀rẹ̀: Ó máa pa dà bẹ̀rẹ̀ àtẹ́tísí náà níbi tó o gbọ́ ọ dé.

Ọ̀wọ́ àwọn àtẹ́tísí tó wà nísàlẹ̀ Audio Program Details ni àwọn àtẹ́tísí míì tó wà ní ìsọ̀rí yẹn. Tẹ Down kó o lè lọ síbẹ̀, tẹ Up kó o lè pa dà síbi Audio Program Details.

 Tẹ́tí sí Àwọn Èyí Tó Wà Lábẹ́ Ìsọ̀rí Kan

Yàtọ̀ sí pé kó o gbọ́ àwọn àtẹ́tísí níkọ̀ọ̀kan, o tún lè tẹ́tí sí gbogbo èyí tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan. Lọ síbi ìsọ̀rí tó o fẹ́ tẹ́tí sí, kó o wá yan ọ̀kan nínú àwọn àbá yìí:

 • Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́.

 • Lọ́kan-ò-jọ̀kan: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn láìtò ó tẹ̀ léra bó ṣe wà lójú tẹlifíṣọ̀n.

Tó o bá ti gbádùn gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn tán, ó máa dáwọ́ dúró.

 Ṣe Àtẹ́tísí Bó O Ṣe Fẹ́

Tí àtẹ́tísí bá ń lọ lọ́wọ́, o lè fi rìmóòtù Amazon Fire TV rẹ ṣe é bó o ṣe fẹ́:

 • Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná: Wàá lè dá àtẹ́tísí dúró. Tó o bá tún tẹ bọ́tìnì yẹn kan náà, ó máa bẹ̀rẹ̀ pa dà.

 • Sún Un Síwájú: Yára sún un lọ sọ́wọ́ ìparí àtẹ́tísí náà. Tẹ Gbádùn Ẹ̀ kó o lè máa wò ó lọ.

 • Sún Un Sẹ́yìn: Sún un pa dà sọ́wọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àtẹ́tísí náà. Tẹ Gbádùn Ẹ̀ kó o lè máa wò ó lọ.

 • Back: Pa dà sí apá Àtẹ́tísí.