Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸLIFÍṢỌ̀N JW

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—Tẹlifíṣọ̀n JW (Lórí Apple TV)

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—Tẹlifíṣọ̀n JW (Lórí Apple TV)

Ó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ láti fi wá a ò tọ̀nà. (Wo ìdálẹ́kọ̀ọ́ Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Apple TV.) Tàbí kó jẹ́ pé kò lè ṣiṣẹ́ lórí tẹlifíṣòn rẹ. Tẹlifíṣọ̀n JW máa ṣiṣẹ́ lórí Apple TV (4th generation).

 

Apple TV (4th generation sókè) ló ń bá Tẹlifíṣọ̀n JW siṣẹ́.

Tó o bá ní kọ̀ǹpútà tàbí fóònù Apple, tàbí tó o ní Apple TV tó ti pẹ́, o lè lo AirPlay láti wo àwọn fídíò lórí tẹlifíṣọ̀n rẹ.

 

Wo àwọn èdè tó wà lórí Apple TV. Tó o bá fẹ́ yan èdè míì, lọ sí Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá tẹ Yan Èdè.

 

Ọ̀fẹ́ lo lè wa ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW jáde, kó o sì lò ó.

 

Ìgbà tó o bá kọ́kọ́ fi orúkọ àkáǹtì rẹ wọlé sórí àwọn Apple Stores (bí iTunes Store, App Store tàbí iBooks Store), ó máa ní kó o yan bó o ṣe fẹ́ máa sanwó, torí kì í ṣe gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ ni ọ̀fẹ́.

Tó ò bá fẹ́ yan bí wàá ṣe máa sanwó lórí àkáǹtì Apple rẹ, tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà ní abala ìrànlọ́wọ́ Apple.

 

Ọ̀rẹ́ rẹ tó mọ̀ nípa Apple TV tàbí Tẹlifíṣọ̀n JW lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ìbéèrè ẹ bá jẹ mọ́ Apple TV tó ò ń lò tàbí àkáǹtì tó o ní lórí ìkànnì, lọ sí abala ìrànlọ́wọ́ lórí ìkànnì Apple. Tó o bá níṣòro pẹ̀lú ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW, jọ̀ọ́, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó sún mọ́ ẹ jù.