TẸLIFÍṢỌ̀N JW
Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Apple TV
Kó o tó lè wo Tẹlifíṣọ̀n JW lórí Apple TV ẹ, àfi kó o kọ́kọ́ ṣètò ẹ̀, kó o sì fi ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Broadcasting sórí ẹ̀. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè bẹ̀rẹ̀:
Ṣètò Apple TV Rẹ
Ìtọ́ni máa bá Apple TV rẹ wá kó o lè ṣètò ẹ̀, kó o sì lè lò ó lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí Apple TV rẹ bá ti wọ orí íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹ̀ lé ìtọní tó bá gbé wá sójú tẹlifíṣọ̀n ẹ kó o lè parí iṣẹ́ lórí ẹ̀.
Fi Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Rẹ̀ Látorí App Store
Lọ sí App Store, kó o wá tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí láti fi ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW sórí ẹ̀:
Fìka fa ojú Siri Remote rẹ sápá Ọ̀tún títí ó fi máa kun Search.
Tẹ ojú rìmóòtù náà kó o lè ṣí àpótí Search, kó o wá fi àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tó wà níbẹ̀ kọ “JW Broadcasting.”
Ọ̀nà míì ni pé, kó o tẹ bọ́tìnì Siri mọ́lẹ̀, kó o wá sọ pé “JW Broadcasting.”
Fìka tẹ ètò ìṣiṣẹ́ náà tó bá ti gbé e wá.
Tẹ̀ lé ìtọ́ni tó bá hàn lójú tẹlifíṣọ̀n rẹ kó o lè fi ètò ìṣiṣẹ́ náà sórí Apple TV ẹ.

