Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW BROADCASTING

Wo fídíò lóríṣiríṣi lórí Amazon Fire TV

Wo fídíò lóríṣiríṣi lórí Amazon Fire TV

O lè wo fídíò èyíkéyìí, wàá sì lè dá a dúró, dá a pa dà sẹ́yìn, sún un síwájú tàbí kó o bọ́ sí èyí tó kàn. O lè wo fídíò kan ṣoṣo tàbí kó o wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan.

(Àkíyèsí: Rìmóòtù tìẹ lè yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú àwòrán inú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.)

 Wá Fídíò, Kó O sì Wò Ó

Tẹ Video Categories lókè kó o lè rí àwọn ìsọ̀rí fídíò tó wà. Fi rìmóòtù Amazon Fire TV rẹ lọ síbi tó o fẹ́ níbi àwọn ìsọ̀rí. Wá tẹ Select kó o lè yan èyí tó o fẹ́.

Àwọn fídíò kan wà tí wàá rí lábẹ́ ìsọ̀rí tó ju ẹyọ kan lọ. Bí àpẹẹrẹ, wàá rí fídíò Ọmọ Onínàákúnàá Pa Dà WáléFídíò, Ìdílé àti Àwọn Ọ̀dọ́.

Tẹ́ bọ́tìnì Shuffle kó o lè máa wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Oríṣiríṣi àkójọ fídíò ló wà ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. Wàá rí àwọn fídíò tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan ní ọ̀wọ́ kan. Àkọlé ìsọ̀rí náà sì máa wà lókè ẹ̀.

Fi rìmóòtù ẹ wá ìsọ̀rí tó o fẹ́:

 • Up àti Down: Lọ sí ìsọ̀rí tó o fẹ́.

 • Left àti Right: Wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan.

Ọ̀nà méjì lo lè gbà wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan:

 • Tẹ bọ́tìnì Gbádùn Gbogbo Ẹ̀ kó o lè wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́.

 • Tẹ bọ́tìnì Shuffle kó o lè máa wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Àkíyèsí: Tó o bá ti wo gbogbo ẹ̀ tán, ó máa dáwọ́ dúró.

Yan fídíò kan kó o lè rí Video Details. Yan ọ̀kan lára àwọn àbá yìí:

 • Gbádùn Ẹ̀: Fídíò náà máa bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀.

 • Gbádùn Gbogbo Ẹ̀. Wàá lè wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́. Tó o bá ti wo gbogbo ẹ̀ tán, ó máa dáwọ́ dúró.

 • Pa Dà Bẹ̀rẹ̀: Ó máa pa dà bẹ̀rẹ̀ fídíò náà níbi tó o wò ó dé.

Ọ̀wọ́ fídíò tó wà nísàlẹ̀ Video Details ni àwọn fídíò míì tó wà ní ìsọ̀rí tó o wà. Tẹ Down kó o lè lọ sí ìsọ̀rí yẹn, tàbí kó o tẹ Up kó o lè pa dà sí Video Details.

 Ṣe Fídíò Bó O Ṣe Fẹ́

Tó o bá ń wo fídíò kan lọ́wọ́, o lè fi rìmóòtù Amazon Fire TV ẹ ṣe é bó o ṣe fẹ́:

 • Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná: Wàá lè dá fídíò náà dúró. Tó o bá tún tẹ bọ́tìnì yẹn kan náà, ó máa bẹ̀rẹ̀ pa dà.

 • Sún un Síwájú tàbí Ọ̀tún: Ó máa sáré sún fídíò náà síwájú dáadáa. Tó bá ti débi tó o fẹ́, tẹ bọ́tìnì Play.

 • Sún Un Sẹ́yìn tàbí Òsì: Ó máa sún fídíò náà pa dà sí ọwọ́ ìbẹ̀rẹ̀. Tó bá ti débi tó o fẹ́, tẹ bọ́tìnì Play.

 • Back: Pa dà sí Video Details.

 Wo Fídíò Tó Wà Tàbí Fídíò Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé

Ní ìbẹ̀rẹ̀ JW Broadcasting, wàá rí ìsọ̀rí méjì pàtàkì níbẹ̀:

 1. Àwọn Ohun Tó Wà: Àwọn fídíò tó fani lọ́kàn mọ́ra, bí àwọn èyí tá a máa ń wò nípàdé wa àárín ọ̀sẹ̀ tàbí nígbà ìjọsìn ìdílé.

 2. Àwọn Fídíò Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé: Àwọn fídíò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí ìkànnì.