Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JW Library Sign Language

JW Library Sign Language

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ètò ìṣiṣẹ́ JW Library Sign Language. O lè fi wa àwọn fídíò èdè adití jáde tàbí kó o wò ó tààràtà látorí ìkànnì jw.org. Ètò ìṣiṣẹ́ yìí tún máa ń ṣètò àwọn fídíò náà.

Wo fídíò Bíbélì àtàwọn ìwé míì lédè adití. Wà á jáde sórí fóònù ẹ kó o lè wò ó nígbà tó ò bá lo íńtánẹ́ẹ̀tì. Wàá gbádùn àwọn àwòrán mèremère tó wà níbẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ pé ó rọrùn láti lò.