Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìpàdé Ìjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Wàá mọ ohun tá a máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa, wàá sì mọ ibi tá a ti ń ṣèpàdé tó sún mọ́ ẹ.

Wá Ibi Tó Sún Mọ́ Ẹ (opens new window)

Kí La Máa Ń Ṣe Láwọn Ìpàdé Wa?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ìpàdé ìjọsìn ní ìgbà méjì lọ́sẹ̀. (Hébérù 10:24, 25) Ní àwọn ìpàdé tó wà fún gbogbo èèyàn yìí, a máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Bíbélì sọ àti bá a ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa.

Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìpàdé náà ló máa ń fún àwọn tó wà níkàlẹ̀ láǹfààní láti sọ̀rọ̀, ńṣe ló máa ń dà bí ìgbà téèyàn wà ní kíláàsì. A kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti sọ̀rọ̀. A máa ń fi orin àti àdúrà bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé náà, a sì máa ń fi parí wọn.

Kò pọn dandan kó o jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o tó lè wá sí àwọn ìpàdé wa. Gbogbo èèyàn la pè láti wá síbẹ̀. Ọ̀fẹ́ làyè ìjókòó. A kì í sì í gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn.