Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìrántí Ikú Jésù

Sunday, March 24, 2024

Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù bó ṣe pa á láṣẹ nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”​—Lúùkù 22:19.

A fẹ́ kó o wá síbi ètò pàtàkì yìí.

Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè

Báwo ni ètò náà ṣe máa pẹ́ tó?

Ó máa tó wákàtí kan.

Ibo lẹ ti máa ṣe é?

Béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ kí wọ́n lè sọ ibi tí wọ́n á ti ṣe é.

Ṣé màá san owó ìwọlé?

Rárá.

Ṣé ẹ máa ń gbégbá ọrẹ?

Rárá. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbégbá ọrẹ láwọn ìpàdé wa.

Ṣé ó nírú aṣọ tí mo gbọ́dọ̀ wọ̀?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò sọ pé irú aṣọ kan làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ wọ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká máa múra lọ́nà tó bójú mu. (1 Tímótì 2:9) Kò pọn dandan kó o wọ aṣọ olówó ńlá tàbí kó o múra bí akọ̀wé.

Báwo lẹ ṣe máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi?

Orin la fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ètò náà tá a sì máa fi parí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀kan lára òjíṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gbàdúrà. Apá kan tó ṣe pàtàkì nígbà Ìrántí Ikú Kristi ni àsọyé kan tó ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí Jésù kú àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa.