Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Ìrànlọ́wọ́ Lórí AndroidTM

Ìrànlọ́wọ́ Lórí AndroidTM

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ètò ìṣiṣẹ́ JW Library. Oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì ló wà lórí ẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 

 

Ohun Tuntun

October 2021 (Version 12.5)

  • Wàá lè wa Ìwé Ìwádìí tuntun jáde lábẹ́ abala ìwádìí nínú Bíbélì

  • ÀKÍYÈSÍ: JW Library Version 12.5 ló máa bá Android 4.1, 4.2, 4.3, 4.4, àti 5.0 ṣiṣẹ́ kẹ́yìn. Tó bá jẹ́ àwọn Android tó ti pẹ́ yìí ni ẹ̀rọ rẹ ń lò, ó máa nílò láti jẹ́ kí Android yẹn gbé pẹ́ẹ́lí sí i kó o lè rí àwọn ohun tuntun tó máa jáde lórí JW Library lọ́jọ́ iwájú wà jáde.

July 2021 (Version 12.4)

  • O ti lè yan èdè tó o fẹ́ kí Ìròyìn Tuntun máa jẹ́.

  • O lè fi ìlujá Ẹsẹ Ojúmọ́ àti Ìpàdé ráńṣẹ́ sí àwọn míì.

  • Ó ti wá túbọ̀ rọrùn láti rí ìsọfúnni nípa àwọn ìtẹ̀jáde tá a ti ṣe àtúnṣe sí.

  • Ìbẹ̀rẹ̀ JW Library ló ti máa rí ìsọfúnni nípa bó o ṣe máa to àwọn nǹkan lórí ètò ìṣiṣẹ́ náà.

January 2021 (Version 12.3)

  • A ti ṣe àtúnṣe sí bí a ṣe kọ àwọn lẹ́tà kó lè túbọ̀ rọrùn láti kà, kó sì jọ bó ṣe rí lórí ìkànnì jw.org.

 

NÍ APÁ YÌÍ

Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè lo àwọn apá pàtàkì nínú ètò ìṣiṣẹ́ JW Library lórí àwọn fóònù Android.

Bó O Ṣe Lè Wa Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè wa Bíbélì jáde lórí JW Library, kó o sì máa lò ó lórí àwọn Android.

Bó O Ṣe Lè Wa Ìwé Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè wa ìwé jáde lórí JW Library, kó o sì máa lò ó lórí àwọn fóònù Android.

Bó O Ṣe Lè Sàmì sí Ìwé​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè sàmì sí ìwé nínú JW Library lórí àwọn fóònù Android.

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè wo àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀ nínú JW Library lórí àwọn fóònù Android.

Pinnu Bó O Ṣe Fẹ́ Kí Ìwé Tó Ò Ń Kà Rí​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè ṣe é kí ìwé tó ò ń kà nínú JW Library rí bó o ṣe fẹ́ kó rí lórí àwọn fóònù Android.

Wá Ọ̀rọ̀ Nínú Bíbélì Tàbí Nínú Ìwé​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè wá ọ̀rọ̀ nínú Bíbélì tàbí ìwé, kó o sì tún wá àkòrí ọ̀rọ̀ ní Insight on the Scriptures nínú JW Library lórí àwọn fóònù Android.

Bó O Ṣe Lè Kun Ọ̀rọ̀​—Lórí Android

Kọ́ bó o ṣe lè kun ọ̀rọ̀ nínú JW Library lórí àwọn fóònù Android.

Bó O Ṣe Lè Fi JW Library Sórí Fóònù Ẹ Tó Ò Bá Tiẹ̀ Lè Ṣí App Store​—Lórí Android

Tó ò bá rí JW Library fi sórí fóònù Android rẹ látorí App Store, o lè wa Android package (APK) rẹ̀ jáde, kó o sì fi sórí fóònù ẹ.

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Library (Lórí Android)

Wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè.