Sáàmù 126:1-6
Orin Ìgòkè.
126 Nígbà tí Jèhófà kó àwọn èèyàn Síónì tó wà lóko ẹrú pa dà,+A rò pé à ń lá àlá ni.
2 Ní àkókò yẹn, ẹ̀rín kún ẹnu wa,Ahọ́n wa sì ń kígbe ayọ̀.+
Ní àkókò yẹn, wọ́n ń sọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé:
“Jèhófà ti ṣe àwọn ohun ńlá fún wọn.”+
3 Jèhófà ti ṣe àwọn ohun ńlá fún wa,+Ayọ̀ wa sì kún.
4 Jèhófà, jọ̀wọ́ kó* àwọn èèyàn wa tó wà lóko ẹrú pa dà,Bí ìṣàn omi tó wà ní Négébù.*
5 Àwọn tó ń fi omijé fúnrúgbìnYóò fi igbe ayọ̀ kórè.
6 Ẹni tó ń jáde, bó tilẹ̀ ń sunkún,Tó gbé àpò irúgbìn rẹ̀ dání,Ó dájú pé ó máa pa dà pẹ̀lú igbe ayọ̀,+Bó ṣe ń gbé àwọn ìtí rẹ̀ wọlé.+

