Sáàmù 135:1-21
135 Ẹ yin Jáà!*
Ẹ yin orúkọ Jèhófà;Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+
2 Ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà,Nínú àwọn àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.+
3 Ẹ yin Jáà, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere.+
Ẹ kọ orin ìyìn* sí orúkọ rẹ̀, nítorí ó dára.
4 Jáà ti yan Jékọ́bù fún ara rẹ̀,Ó ti yan Ísírẹ́lì ṣe ohun ìní rẹ̀ pàtàkì.*+
5 Mo mọ̀ dáadáa pé Jèhófà tóbi;Olúwa wa ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+
6 Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́+Ní ọ̀run àti ní ayé, nínú òkun àti nínú gbogbo ibú omi.
7 Ó ń mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé;Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò;Ó ń mú ẹ̀fúùfù jáde látinú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+
8 Ó pa àwọn àkọ́bí Íjíbítì,Àti èèyàn àti ẹranko.+
9 Ó rán àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sáàárín rẹ, ìwọ Íjíbítì,+Sí Fáráò àti sí gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀.+
10 Ó pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè+ run,Ó sì pa àwọn ọba alágbára+
11 —Síhónì ọba àwọn Ámórì,+Ógù ọba Báṣánì+Àti gbogbo àwọn ìjọba Kénáánì.
12 Ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún,Ó fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn rẹ̀.+
13 Jèhófà, orúkọ rẹ wà títí láé.
Jèhófà, òkìkí rẹ yóò máa kàn* láti ìran dé ìran.+
14 Nítorí Jèhófà yóò gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀,*+Yóò sì ṣàánú* àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+
15 Àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè jẹ́ fàdákà àti wúrà,Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+
16 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;
17 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn.
Kò sí èémí kankan ní ẹnu wọn.+
18 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+
19 Ilé Ísírẹ́lì, ẹ yin Jèhófà.
Ilé Áárónì, ẹ yin Jèhófà.
20 Ilé Léfì, ẹ yin Jèhófà.+
Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yin Jèhófà.
21 Ìyìn ni fún Jèhófà láti Síónì,+Ẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+
Ẹ yin Jáà!+

