Sáàmù 146:1-10

  • Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn

    • Nígbà tí èèyàn bá kú, èrò inú rẹ̀ á ṣègbé (4)

    • Ọlọ́run ń gbé àwọn tó sorí kodò dìde (8)

146  Ẹ yin Jáà!*+ Kí gbogbo ara* mi yin Jèhófà.+  Màá yin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi. Màá kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run mi nígbà tí mo bá wà láàyè.  Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí*Tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là.+  Ẹ̀mí* rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀;+Ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.+  Aláyọ̀ ni ẹni tí Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,+Tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+  Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé,Òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn,+Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo,+  Ẹni tó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì,Ẹni tó ń fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ.+ Jèhófà ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n* sílẹ̀.+  Jèhófà ń la ojú àwọn afọ́jú;+Jèhófà ń gbé àwọn tó sorí kọ́ dìde;+Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.  Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àjèjì;Ó ń fún ọmọ aláìníbaba àti opó lókun,+Àmọ́, ó ń sọ èrò àwọn ẹni burúkú dòfo.*+ 10  Jèhófà yóò jẹ Ọba títí láé,+Àní Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì, láti ìran dé ìran. Ẹ yin Jáà!*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “kọrin.”
Tàbí “èèyàn pàtàkì.”
Tàbí “Èémí.”
Ní Héb., “àwọn tí a dè.”
Tàbí “sọ ọ̀nà àwọn ẹni burúkú di wíwọ́.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.