Sáàmù 64:1-10

  • Ààbò lọ́wọ́ àtakò tó fara sin

    • “Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà” (7)

Sí olùdarí. Orin Dáfídì. 64  Gbọ́ ohùn mi Ọlọ́run, bí mo ṣe ń bẹ̀bẹ̀.+ Yọ mí nínú ìbẹ̀rù ọ̀tá.   Dáàbò bò mí lọ́wọ́ ohun tí àwọn ẹni ibi ń gbèrò ní ìkọ̀kọ̀,+Lọ́wọ́ àwùjọ àwọn aṣebi.   Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà;Wọ́n dojú ọ̀rọ̀ burúkú wọn kọni bí ọfà,   Kí wọ́n lè ta aláìlẹ́bi lọ́fà láti ibi tí wọ́n fara pa mọ́ sí;Wọ́n ta á lọ́fà lójijì, láìbẹ̀rù.   Wọn ò jáwọ́ nínú èrò ibi wọn;*Wọ́n sọ bí wọ́n ṣe máa dẹ pańpẹ́ wọn pa mọ́. Wọ́n sọ pé: “Ta ló máa rí wọn?”+   Wọ́n ń wá ọ̀nà tuntun láti ṣe ohun tí kò tọ́;Wọ́n ń hùmọ̀ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn ní ìkọ̀kọ̀;+Inú kálukú wọn jìn.   Àmọ́ Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà;+Ọfà yóò dọ́gbẹ́ sí wọn lára lójijì,   Ahọ́n àwọn fúnra wọn yóò mú kí wọ́n ṣubú;+Gbogbo àwọn tó ń wò wọ́n yóò mi orí.   Nígbà náà, ẹ̀rù á ba gbogbo èèyàn,Wọ́n á máa kéde ohun tí Ọlọ́run ti ṣe,Wọ́n á sì lóye àwọn iṣẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀.+ 10  Olódodo á máa yọ̀ nínú Jèhófà, á sì fi í ṣe ibi ààbò rẹ̀;+Gbogbo àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin á máa ṣògo.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Wọ́n fún ara wọn ní ìṣírí láti ṣe ibi.”
Tàbí “yangàn.”