Sáàmù 74:1-23
Másíkílì.* Ti Ásáfù.+
74 Ọlọ́run, kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?+
Kí nìdí tí ìbínú rẹ fi ń jó bí iná* lórí agbo ẹran tó wà ní ibi ìjẹko rẹ?+
2 Rántí àwọn èèyàn* tí o ti yàn tipẹ́tipẹ́,+Ẹ̀yà tí o rà pa dà láti fi ṣe ogún rẹ.+
Rántí Òkè Síónì, ibi tí o gbé.+
3 Lọ sí àwọn ibi tó fìgbà gbogbo jẹ́ àwókù.+
Ọ̀tá ti ba gbogbo ohun tó wà ní ibi mímọ́ jẹ́.+
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù nínú ibi ìpàdé* rẹ.+
Wọ́n fi àwọn ọ̀págun wọn ṣe àmì síbẹ̀.
5 Wọ́n dà bí àwọn ọkùnrin tó ń fi àáké dá igbó kìjikìji lu.
6 Wọ́n fi àáké àti àwọn ọ̀pá onírin fọ́ àwọn iṣẹ́ ọnà ara rẹ̀.+
7 Wọ́n sọ iná sí ibi mímọ́ rẹ.+
Wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn tí o fi orúkọ rẹ pè di aláìmọ́, wọ́n sì wó o lulẹ̀.
8 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn sọ nínú ọkàn wọn pé:
“Gbogbo ibi ìpàdé tó jẹ́ ti Ọlọ́run* ní ilẹ̀ náà la máa dáná sun.”
9 Kò sí àmì kankan tí a rí;Kò sí wòlíì kankan mọ́,Kò sì sí ẹnì kankan nínú wa tó mọ bí èyí ṣe máa pẹ́ tó.
10 Ọlọ́run, ìgbà wo ni elénìní máa pẹ̀gàn rẹ dà?+
Ṣé ọ̀tá yóò máa hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ títí láé ni?+
11 Kí ló dé tí o fi fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?+
Nà án jáde láti àyà rẹ,* kí o sì pa wọ́n run.
12 Àmọ́, Ọlọ́run ni Ọba mi láti ayébáyé,Ẹni tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà ní ayé.+
13 O fi agbára rẹ ru òkun sókè;+O fọ́ orí àwọn ẹran ńlá inú òkun.
14 O fọ́ orí Léfíátánì;*O fi ṣe oúnjẹ fún àwọn èèyàn, fún àwọn tó ń gbé aṣálẹ̀.
15 O la ọ̀nà fún àwọn ìsun omi àti odò;+O mú kí àwọn odò tó ń ṣàn nígbà gbogbo gbẹ táútáú.+
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni òru.
Ìwọ lo ṣe ìmọ́lẹ̀* àti oòrùn.+
17 O pa ààlà sí gbogbo ayé;+O ṣe ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.+
18 Jèhófà, rántí bí ọ̀tá ṣe pẹ̀gàn rẹ,Bí àwọn òmùgọ̀ ṣe hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ.+
19 Má ṣe fi ẹ̀mí* oriri rẹ fún àwọn ẹranko.
Ní ti ẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ tí ìyà ń jẹ, má ṣe gbàgbé rẹ̀ títí láé.
20 Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá,Nítorí pé àwọn ibi tó ṣókùnkùn ní ayé ti di ibùgbé àwọn oníwà ipá.
21 Kí ẹni tí a ni lára má ṣe yíjú pa dà nítorí ìjákulẹ̀;+Kí aláìní àti tálákà máa yin orúkọ rẹ.+
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò.
Rántí bí àwọn òmùgọ̀ ṣe ń pẹ̀gàn rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
23 Má gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá rẹ ń sọ.
Ariwo àwọn tó ń pè ọ́ níjà ń lọ sókè nígbà gbogbo.

