Sáàmù 118:1-29
118 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.
2 Kí Ísírẹ́lì sọ pé:
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”
3 Kí àwọn ará ilé Áárónì sọ pé:
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”
4 Kí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà sọ pé:
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”
5 Mo ké pe Jáà* nínú wàhálà mi;Jáà dá mi lóhùn, ó sì mú mi wá síbi ààbò.*+
6 Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.+
Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?+
7 Jèhófà wà lẹ́yìn mi láti ràn mí lọ́wọ́;*+Màá rí ìṣubú àwọn tó kórìíra mi.+
8 Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbòJu láti gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn.+
9 Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbòJu láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí.+
10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi ká,Àmọ́ ní orúkọ Jèhófà,Mo lé wọn sẹ́yìn.+
11 Wọ́n yí mi ká, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n yí mi ká pátápátá,Àmọ́ ní orúkọ Jèhófà,Mo lé wọn sẹ́yìn.
12 Wọ́n yí mi ká bí oyin,Àmọ́ wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún.
Ní orúkọ Jèhófà,Mo lé wọn sẹ́yìn.+
13 Wọ́n* fi agbára tì mí kí n lè ṣubú,Àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́.
14 Jáà ni ibi ààbò mi àti agbára mi,Ó sì ti di ìgbàlà mi.+
15 Ìró ayọ̀ àti ti ìgbàlà*Wà ní àgọ́ àwọn olódodo.
Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ hàn.+
16 Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń ṣẹ́gun;Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ hàn.+
17 Mi ò ní kú, ṣe ni màá wà láàyè,Kí n lè máa kéde àwọn iṣẹ́ Jáà.+
18 Jáà bá mi wí gan-an,+Àmọ́ kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.+
19 Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè òdodo fún mi;+Màá wọ inú wọn, màá sì yin Jáà.
20 Ẹnubodè Jèhófà nìyí.
Olódodo yóò gba ibẹ̀ wọlé.+
21 Màá yìn ọ́, nítorí o dá mi lóhùn,+O sì di ìgbàlà mi.
22 Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀Ti di olórí òkúta igun ilé.*+
23 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá;+Ó jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.+
24 Ọjọ́ tí Jèhófà dá nìyí;Inú wa yóò máa dùn, a ó sì máa yọ̀ nínú rẹ̀.
25 Jèhófà, a bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ gbà wá!
Jèhófà, jọ̀wọ́ fún wa ní ìṣẹ́gun!
26 Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà;+À ń bù kún yín látinú ilé Jèhófà.
27 Jèhófà ni Ọlọ́run;Ó ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀.+
Ẹ já ewé dání, kí ẹ sì dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ síbi àjọyọ̀,+Títí dé ibi àwọn ìwo pẹpẹ.+
28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, màá yìn ọ́;Ìwọ Ọlọ́run mi, màá gbé ọ ga.+
29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ nítorí ó jẹ́ ẹni rere;Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

