Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 15

Báwo Lo Ṣe Lè Láyọ̀?

“Oúnjẹ tí a fi nǹkan ọ̀gbìn sè níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju akọ màlúù àbọ́sanra níbi tí ìkórìíra wà.”

Òwe 15:17

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.”

Àìsáyà 48:17

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.”

Mátíù 5:3

“Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”

Mátíù 22:39

“Bí ẹ ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.”

Lúùkù 6:31

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”

Lúùkù 11:28

“Tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”

Lúùkù 12:15

“Torí náà, tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.”

1 Tímótì 6:8

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”

Ìṣe 20:35