Sáàmù 125:1-5
Orin Ìgòkè.
125 Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+Dà bí Òkè Síónì, tí kò ṣeé mì,Àmọ́ tí ó wà títí láé.+
2 Bí àwọn òkè ṣe yí Jerúsálẹ́mù ká,+Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yí àwọn èèyàn rẹ̀ ká+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
3 Ọ̀pá àṣẹ ìwà burúkú kò ní máa wà lórí ilẹ̀ tí a pín fún àwọn olódodo,+Kí àwọn olódodo má bàa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe* ohun tí kò tọ́.+
4 Jèhófà, ṣe rere sí àwọn ẹni rere,+Sí àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+
5 Ní ti àwọn tó yà sí ọ̀nà àìtọ́,Jèhófà yóò mú wọn kúrò pẹ̀lú àwọn aṣebi.+
Kí àlàáfíà wà ní Ísírẹ́lì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “rawọ́ lé.”

