Sáàmù 15:1-5
Orin Dáfídì.
15 Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?
Ta ló lè máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?+
2 Ẹni tó ń rìn láìlẹ́bi,*+Tó ń ṣe ohun tí ó tọ́+Tó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn rẹ̀.+
3 Kò fi ahọ́n rẹ̀ bani jẹ́,+Kò ṣe ohun búburú kankan sí ọmọnìkejì rẹ̀,+Kò sì ba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórúkọ jẹ́.*+
4 Kì í bá ẹnikẹ́ni tó jẹ́ oníwàkiwà kẹ́gbẹ́,+Àmọ́ ó máa ń bọlá fún àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà.
Kì í yẹ àdéhùn,* kódà tó bá máa pa á lára.+
5 Kì í yáni lówó èlé,+Kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti gbógun ti aláìṣẹ̀.+
Ẹni tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, mìmì kan ò ní mì í láé.*+

