Sáàmù 25:1-22
Ti Dáfídì.
א [Áléfì]
25 Jèhófà, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo yíjú* sí.
ב [Bétì]
2 Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+Má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí.+
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi yọ̀ mí.+
ג [Gímélì]
3 Ó dájú pé ojú ò ní ti ìkankan nínú àwọn tó nírètí nínú rẹ,+Àmọ́ ojú á ti àwọn tó jẹ́ oníbékebèke láìnídìí.+
ד [Dálétì]
4 Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà;+Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.+
ה [Híì]
5 Mú kí n máa rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi,+Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.
ו [Wọ́ọ̀]
Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
ז [Sáyìn]
6 Jèhófà, rántí àánú rẹ àti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+Èyí tí ò ń fi hàn nígbà gbogbo.*+
ח [Hétì]
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi àti àwọn àṣìṣe mi.
Rántí mi nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+Nítorí oore rẹ, Jèhófà.+
ט [Tétì]
8 Ẹni rere àti adúróṣinṣin ni Jèhófà.+
Ìdí nìyẹn tó fi ń kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n tọ̀.+
י [Yódì]
9 Yóò darí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́,*+Yóò sì kọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ní ọ̀nà rẹ̀.+
כ [Káfì]
10 Gbogbo ọ̀nà Jèhófà jẹ́ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́Fún àwọn tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀+ àti àwọn ìránnilétí+ rẹ̀ mọ́.
ל [Lámédì]
11 Nítorí orúkọ rẹ, Jèhófà,+Dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pọ̀.
מ [Mémì]
12 Ta ni ẹni tó ń bẹ̀rù Jèhófà?+
Òun yóò kọ́ ẹni náà ní ọ̀nà tó yẹ kí ó yàn.+
נ [Núnì]
13 Yóò* gbádùn ohun rere,+Àwọn àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ yóò sì jogún ayé.+
ס [Sámékì]
14 Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́,+Ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ májẹ̀mú rẹ̀.+
ע [Áyìn]
15 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ojú mi ń wò nígbà gbogbo,+Nítorí ó máa yọ ẹsẹ̀ mi nínú àwọ̀n.+
פ [Péè]
16 Bojú wò mí, kí o sì ṣojú rere sí mi,Nítorí mo dá wà, mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́.
צ [Sádì]
17 Ìdààmú ọkàn mi ti pọ̀ sí i;+Yọ mí nínú másùnmáwo tó bá mi.
ר [Réṣì]
18 Wo ìpọ́njú mi àti wàhálà mi,+Kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.+
19 Wo bí àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó,Àti bí ìkórìíra tí wọ́n ní sí mi ṣe lágbára tó.
ש [Ṣínì]
20 Ṣọ́ ẹ̀mí* mi, kí o sì gbà mí sílẹ̀.+
Má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí, nítorí ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.
ת [Tọ́ọ̀]
21 Kí ìwà títọ́ àti ìdúróṣinṣin máa dáàbò bò mí,+Nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+
22 Ọlọ́run, gba Ísírẹ́lì kúrò* nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.

