Sáàmù 79:1-13

  • Àdúrà ìgbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ya bo àwọn èèyàn Ọlọ́run

    • “A ti di ẹni ẹ̀gàn” (4)

    • ‘Ràn wá lọ́wọ́ nítorí orúkọ rẹ’ (9)

    • “San án pa dà fún àwọn aládùúgbò wa ní ìlọ́po méje” (12)

Orin Ásáfù.+ 79  Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti ya wọnú ogún rẹ;+Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin;+Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di àwókù.+   Wọ́n ti fi òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run,Wọ́n sì ti fi ẹran ara àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ fún àwọn ẹran inú igbó.+   Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi káàkiri Jerúsálẹ́mù,Kò sì sí ẹni tó ṣẹ́ kù tó máa sin wọ́n.+   A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;+Àwọn tó yí wa ká ń fi wá ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.   Jèhófà, ìgbà wo lo máa bínú dà? Ṣé títí láé ni?+ Ìgbà wo ni ìbínú ńlá rẹ máa jó bí iná dà?+   Da ìrunú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́Àti sórí àwọn ìjọba tí kì í ké pe orúkọ rẹ.+   Nítorí wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run,Wọ́n sì ti sọ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ di ahoro.+   Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa sí wa lọ́rùn.+ Tètè wá ṣàánú wa,+Torí wọ́n ti bá wa kanlẹ̀.   Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run ìgbàlà wa,+Nítorí orúkọ rẹ ológo;Gbà wá sílẹ̀, kí o sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá* nítorí orúkọ rẹ.+ 10  Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè á fi sọ pé: “Ọlọ́run wọn dà?”+ Níṣojú wa, jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ péO ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ta sílẹ̀.+ 11  Gbọ́ ìkérora àwọn ẹlẹ́wọ̀n.+ Fi agbára ńlá* rẹ dáàbò bo* àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún.*+ 12  San án pa dà fún àwọn aládùúgbò wa ní ìlọ́po méje+Nítorí ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá ọ, Jèhófà.+ 13  Nígbà náà, àwa èèyàn rẹ àti agbo ẹran ibi ìjẹko rẹ+Yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;A ó sì máa kéde ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀.”
Ní Héb., “apá.”
Tàbí kó jẹ́, “dá . . . sílẹ̀.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ikú.”