Sáàmù 116:1-19

  • Orin ọpẹ́

    • “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà?” (12)

    • “Màá gbé ife ìgbàlà” (13)

    • “Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà” (14, 18)

    • Àdánù ńlá ni ikú àwọn adúróṣinṣin (15)

116  Mo nífẹ̀ẹ́ JèhófàNítorí ó ń gbọ́* ohùn mi, ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+   Nítorí ó ń tẹ́tí* sí mi,+Èmi yóò máa ké pè é ní gbogbo ìgbà tí mo bá wà láàyè.*   Àwọn okùn ikú yí mi ká;Isà Òkú dì mí mú.*+ Ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn bò mí mọ́lẹ̀.+   Àmọ́ mo ké pe orúkọ Jèhófà,+ mo ní: “Jèhófà, gbà mí* sílẹ̀!”   Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti olódodo;+Ọlọ́run wa jẹ́ aláàánú.+   Jèhófà ń ṣọ́ àwọn aláìmọ̀kan.+ Wọ́n rẹ̀ mí sílẹ̀, àmọ́ ó gbà mí.   Kí ọkàn* mi rí ìsinmi lẹ́ẹ̀kan sí i,Nítorí Jèhófà ti fi inú rere hàn sí mi.   O ti gbà mí* lọ́wọ́ ikú,O gba ojú mi lọ́wọ́ omijé, o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìkọ̀sẹ̀.+   Ṣe ni èmi yóò máa rìn níwájú Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè. 10  Mo nígbàgbọ́, torí náà mo sọ̀rọ̀;+Ìyà jẹ mí gan-an. 11  Ní tèmi, jìnnìjìnnì bò mí, mo sọ pé: “Òpùrọ́ ni gbogbo èèyàn.”+ 12  Kí ni màá san pa dà fún JèhófàLórí gbogbo oore tó ṣe fún mi? 13  Màá gbé ife ìgbàlà,*Màá sì ké pe orúkọ Jèhófà. 14  Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún JèhófàNíwájú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+ 15  Lójú Jèhófà, àdánù ńlá*Ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+ 16  Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà,Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni mí. Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ. O ti tú ìdè mi.+ 17  Màá rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ;+Màá ké pe orúkọ Jèhófà. 18  Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà+Níwájú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀,+ 19  Nínú àwọn àgbàlá ilé Jèhófà,+Láàárín rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù. Ẹ yin Jáà!*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “Mo nífẹ̀ẹ́ nítorí Jèhófà ń gbọ́.”
Tàbí “ó ń bẹ̀rẹ̀ kí ó lè fetí.”
Ní Héb., “ní ọjọ́ ayé mi.”
Ní Héb., “Àwọn ìdààmú Ṣìọ́ọ̀lù wá mi rí.”
Tàbí “gba ọkàn mi.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “gba ọkàn mi.”
Tàbí “ìgbàlà ńlá.”
Ní Héb., “iyebíye.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.