Sáàmù 9:1-20
Sí olùdarí; lórí Muti-lábénì.* Orin Dáfídì.
א [Áléfì]
9 Jèhófà, màá fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́;Màá sọ nípa gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+
2 Ṣe ni inú mi á máa dùn, tí màá sì máa yọ̀ nínú rẹ;Màá fi orin yin* orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ.+
ב [Bétì]
3 Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi bá sá pa dà,+Wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì ṣègbé kúrò níwájú rẹ.
4 Nítorí pé o gbèjà mi lórí ẹ̀tọ́ mi;O jókòó sórí ìtẹ́ rẹ, o sì ń fi òdodo ṣe ìdájọ́.+
ג [Gímélì]
5 O ti bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,+ o sì ti pa àwọn ẹni burúkú run,O ti nu orúkọ wọn kúrò títí láé àti láéláé.
6 Ọ̀tá ti pa run títí láé;O ti fa àwọn ìlú wọn tu,Wọn yóò sì di ẹni ìgbàgbé.+
ה [Híì]
7 Àmọ́ Jèhófà wà lórí ìtẹ́ títí láé;+Ó ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in láti máa ṣe ìdájọ́ òdodo.+
8 Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé;*+Yóò dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè.+
ו [Wọ́ọ̀]
9 Jèhófà yóò di ibi ààbò* fún àwọn tí à ń ni lára,+Ibi ààbò ní àkókò wàhálà.+
10 Àwọn tó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀ lé ọ;+Jèhófà, ìwọ kì yóò pa àwọn tó ń wá ọ tì láé.+
ז [Sáyìn]
11 Ẹ kọ orin ìyìn sí Jèhófà, ẹni tó ń gbé ní Síónì;Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe.+
12 Nítorí Ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wọn ń rántí wọn;+Kò ní gbàgbé igbe àwọn tí ìyà ń jẹ.+
ח [Hétì]
13 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà; wo ìyà tí àwọn tó kórìíra mi fi ń jẹ mí,Ìwọ tó gbé mi dìde láti àwọn ẹnubodè ikú,+
14 Kí n lè máa kéde àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó yẹ fún ìyìn ní àwọn ẹnubodè ọmọbìnrin Síónì,+Kí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ sì lè máa mú inú mi dùn.+
ט [Tétì]
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti rì sínú kòtò tí wọ́n gbẹ́;Ẹsẹ̀ wọn ti kó sínú àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ pa mọ́.+
16 Àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà ń mú ṣẹ ń jẹ́ kí a mọ̀ ọ́n.+
Iṣẹ́ ọwọ́ ẹni burúkú ti dẹkùn mú òun fúnra rẹ̀.+
Hígáíónì.* (Sélà)
י [Yódì]
17 Àwọn èèyàn burúkú á sá pa dà, wọ́n á sì forí lé Isà Òkú,*Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Àmọ́, a kò ní gbàgbé àwọn aláìní títí lọ;+Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ kò ní já sí asán láé.+
כ [Káfì]
19 Dìde, Jèhófà! Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí.
Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè gba ìdájọ́ níwájú rẹ.+
20 Dẹ́rù bà wọ́n, Jèhófà,+Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ẹni kíkú lásán ni wọ́n. (Sélà)
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kọ orin sí.”
^ Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
^ Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

