Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 8

Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

“Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!”

Jóòbù 34:10

“Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ló ń dán mi wò.’ Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.”

Jémíìsì 1:13

“Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”

1 Pétérù 5:7

“Jèhófà kò fi ìlérí rẹ̀ falẹ̀, bí àwọn èèyàn kan ṣe rò pé ó ń fi falẹ̀, àmọ́ ó ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.”

2 Pétérù 3:9