Sáàmù 3:1-8

  • Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run kódà nínú ewu

    • ‘Kí nìdí tí àwọn ọ̀tá fi pọ̀ tó báyìí?’ (1)

    • “Ti Jèhófà ni ìgbàlà” (8)

Orin tí Dáfídì kọ nígbà tó ń sá lọ nítorí Ábúsálómù ọmọ rẹ̀.+ 3  Jèhófà, kí nìdí tí àwọn ọ̀tá mi fi pọ̀ tó báyìí?+ Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń dìde sí mi?+   Ọ̀pọ̀ ń sọ nípa mi* pé: “Ọlọ́run ò ní gbà á sílẹ̀.”+ (Sélà)*   Àmọ́, ìwọ Jèhófà ni apata tó yí mi ká,+Ògo mi+ àti Ẹni tó ń gbé orí mi sókè.+   Màá ké pe Jèhófà,Yóò sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀.+ (Sélà)   Màá dùbúlẹ̀, màá sùn;Màá sì jí ní àlàáfíà,Nítorí Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn.+   Mi ò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyànTí wọ́n yí mi ká láti gbógun tì mí.+   Dìde, Jèhófà! Gbà mí sílẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run mi! Nítorí wàá gbá gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́;Wàá ká eyín àwọn ẹni burúkú.+   Ti Jèhófà ni ìgbàlà.+ Ìbùkún rẹ wà lórí àwọn èèyàn rẹ. (Sélà)

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn mi.”