Sáàmù 30:1-12

  • Ọ̀fọ̀ yí pa dà di ìdùnnú

    • Ojú rere Ọlọ́run wà títí ọjọ́ ayé (5)

Orin. Orin ìṣílé. Ti Dáfídì. 30  Màá gbé ọ ga, Jèhófà, nítorí o ti gbé mi* sókè,O ò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi yọ̀ mí.+   Jèhófà Ọlọ́run mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, o sì wò mí sàn.+   Jèhófà, o ti gbé mi* sókè látinú Isà Òkú.*+ O mú kí n wà láàyè, o ò sì jẹ́ kí n rì sínú kòtò.*+   Ẹ fi orin yin* Jèhófà, ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,+Ẹ fi ọpẹ́ fún orúkọ* mímọ́ rẹ̀;+   Nítorí ìbínú rẹ̀ lórí èèyàn kì í pẹ́ rárá,+Àmọ́ ojú rere* rẹ̀ sí èèyàn wà títí ọjọ́ ayé.+ Ẹkún lè wà ní àṣálẹ́, àmọ́ tó bá di àárọ̀, igbe ayọ̀ á sọ.+   Nígbà tí kò sí ìdààmú kankan fún mi, mo sọ pé: “Mìmì kan ò ní mì mí.”*   Jèhófà, nígbà tí o ṣojú rere sí mi,* o mú kí n lágbára bí òkè.+ Àmọ́ nígbà tí o fi ojú rẹ pa mọ́, jìnnìjìnnì bá mi.+   Jèhófà, ìwọ ni mò ń ké pè;+Jèhófà ni mo sì ń bẹ̀ fún ojú rere.   Èrè wo ló wà nínú ikú* mi, nínú bí mo ṣe ń lọ sínú kòtò?*+ Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?+ Ṣé ó lè sọ nípa ìṣòtítọ́ rẹ?+ 10  Fetí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì ṣojú rere sí mi.+ Jèhófà, wá ràn mí lọ́wọ́.+ 11  O ti sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó;O ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀* mi, o sì fi aṣọ ìdùnnú wọ̀ mí, 12  Kí n* lè máa kọrin ìyìn rẹ, kí n má sì dákẹ́. Jèhófà Ọlọ́run mi, èmi yóò máa yìn ọ́ títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “fà mí.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “kọrin sí.”
Ní Héb., “ìrántí.”
Tàbí “inú rere.”
Tàbí “Mi ò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”
Tàbí “fi inú rere hàn sí mi.”
Ní Héb., “ẹ̀jẹ̀.”
Tàbí “sàréè.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ògo mi.”