Sáàmù 124:1-8
Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.
124 “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni”+—Kí Ísírẹ́lì sọ pé—
2 “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni+Nígbà tí àwọn èèyàn dìde láti bá wa jà,+
3 Wọn ì bá ti gbé wa mì láàyè+Nígbà tí inú wọn ń ru sí wa.+
4 Omi ì bá ti gbé wa lọ,Ọ̀gbàrá ì bá ti ṣàn kọjá lórí wa.*+
5 Omi tó ń ru gùdù ì bá ti bò wá* mọ́lẹ̀.
6 Ìyìn ni fún Jèhófà,Torí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún eyín wọn.
7 A* dà bí ẹyẹ tó bọ́Nínú pańpẹ́ ọdẹ;+Pańpẹ́ náà ṣẹ́,A sì bọ́.+
8 Ìrànlọ́wọ́ wa wà nínú orúkọ Jèhófà,+Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.”