Sáàmù 42:1-11

  • Yíyin Ọlọ́run tó jẹ́ Olùgbàlà Atóbilọ́lá

    • Mò ń wá Ọlọ́run bí àgbọ̀nrín ṣe ń wá omi (1, 2)

    • “Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí mi?” (5, 11)

    • “Dúró de Ọlọ́run” (5, 11)

Sí olùdarí. Másíkílì* àwọn ọmọ Kórà.+ 42  Bí ọkàn àgbọ̀nrín ṣe máa ń fà sí odò,Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ṣe ń fà sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi.   Mò* ń wá Ọlọ́run, Ọlọ́run alààyè, bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ ṣe ń wá omi.+ Ìgbà wo ni kí n wá, kí n sì fara hàn níwájú Ọlọ́run?+   Omijé mi ni oúnjẹ mi lọ́sàn-án àti lóru;Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń fi mí ṣẹ̀sín, wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+   Mo rántí àwọn nǹkan yìí, mo sì tú ọkàn* mi jáde,Torí pé, nígbà kan, mo ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn rìn;Mo máa ń rìn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀* níwájú wọn lọ sí ilé Ọlọ́run,Pẹ̀lú igbe ayọ̀ àti ti ọpẹ́,Ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń ṣàjọyọ̀.+   Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí* mi?+ Kí nìdí tí ìdààmú fi bá ọkàn mi? Dúró de Ọlọ́run,+Nítorí mo ṣì máa yìn ín torí òun ni Olùgbàlà mi Atóbilọ́lá.+   Ọlọ́run mi, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá ẹ̀mí* mi.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi rántí rẹ,+Láti ilẹ̀ Jọ́dánì àti àwọn téńté orí Hámónì,Láti Òkè Mísárì.*   Ibú omi ń pe ibú omiNígbà tí àwọn omi rẹ tó ń dà ṣọ̀ọ̀rọ̀ ń dún. Gbogbo omi rẹ tó ń ru gùdù ti bò mí mọ́lẹ̀.+   Ní ọ̀sán, Jèhófà yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,Ní òru, orin rẹ̀ yóò wà lẹ́nu mi, ìyẹn àdúrà sí Ọlọ́run tó fún mi ní ẹ̀mí.+   Màá sọ fún Ọlọ́run, àpáta mi pé: “Kí nìdí tí o fi gbàgbé mi?+ Kí nìdí tí mo fi ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ nítorí pé ọ̀tá mi ń ni mí lára?”+ 10  Àwọn ọ̀tá mi ń fi mí ṣẹ̀sín nítorí ìkórìíra tó lágbára tí wọ́n ní sí mi;*Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń fi mí ṣẹ̀sín, wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+ 11  Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí* mi? Kí nìdí tí ìdààmú fi bá ọkàn mi? Dúró de Ọlọ́run,+Nítorí mo ṣì máa yìn ín torí òun ni Olùgbàlà mi Atóbilọ́lá àti Ọlọ́run mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “máa ń rọra rìn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “òkè kékeré.”
Tàbí kó jẹ́, “bíi pé wọ́n ń fọ́ egungun mi.”
Tàbí “ọkàn.”