Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 18

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn yóò wá.”

Sáàmù 65:2

“Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.”

Òwe 3:5, 6

“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”

Jòhánù 17:3

“Ní tòótọ́, [Ọlọ́run] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”

Ìṣe 17:27

“Ohun tí mò ń gbà ládùúrà ni pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi, kí ẹ sì ní ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́.”

Fílípì 1:9

“Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn tó bá ń fúnni.”

Jémíìsì 1:5

“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ sì wẹ ọkàn yín mọ́, ẹ̀yin aláìnípinnu.”

Jémíìsì 4:8

“Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira.”

1 Jòhánù 5:3