Sáàmù 20:1-9
-
Ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn rí ìgbàlà
-
Àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin, “àmọ́ àwa ń ké pe orúkọ Jèhófà” (7)
-
Sí olùdarí. Orin Dáfídì.
20 Kí Jèhófà dá ọ lóhùn ní ọjọ́ wàhálà.
Kí orúkọ Ọlọ́run Jékọ́bù dáàbò bò ọ́.+
2 Kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ibi mímọ́,+Kó sì gbé ọ ró láti Síónì.+
3 Kó rántí gbogbo ọrẹ ẹ̀bùn rẹ;Kó fi ojú rere gba ẹbọ sísun rẹ.* (Sélà)
4 Kó fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ fẹ́,+Kó sì mú kí gbogbo èrò* rẹ ṣẹ.
5 A ó kígbe ayọ̀ nítorí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ;+A ó gbé àwọn ọ̀págun wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.+
Kí Jèhófà dáhùn gbogbo ohun tí o béèrè.
6 Mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ń gba ẹni àmì òróró rẹ̀ sílẹ̀.+
Ó ń dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́Pẹ̀lú ìgbàlà* ńlá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.+
7 Àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn míì sì gbẹ́kẹ̀ lé ẹṣin,+Àmọ́, àwa ń ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.+
8 Wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú lulẹ̀,Àmọ́ àwa ti dìde, a sì ti kọ́fẹ pa dà.+
9 Jèhófà, gba ọba sílẹ̀!+
Yóò dá wa lóhùn ní ọjọ́ tí a bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́.+

