Sáàmù 109:1-31

  • Àdúrà ẹni tí ìdààmú bá

    • ‘Kí ẹlòmíì gba ipò rẹ̀’ (8)

    • Ọlọ́run dúró ti aláìní (31)

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin. 109  Ìwọ Ọlọ́run tí mò ń yìn,+ má ṣe dákẹ́.   Nítorí àwọn ẹni burúkú àti àwọn ẹlẹ́tàn ń la ẹnu wọn sí mi. Wọ́n ń fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ nípa mi;+   Wọ́n yí mi ká, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìkórìíra sí mi,Wọ́n ń bá mi jà láìnídìí.+   Mo nífẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń ta kò mí;+Síbẹ̀ mi ò dákẹ́ àdúrà.   Wọ́n ń fi ibi san ire fún mi,+Wọ́n sì ń fi ìkórìíra san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.+   Yan ẹni burúkú lé e lórí;Kí alátakò* dúró sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.   Nígbà tí wọ́n bá ṣèdájọ́ rẹ̀, kí ó jẹ̀bi;*Kí á ka àdúrà rẹ̀ pàápàá sí ẹ̀ṣẹ̀.+   Kí ẹ̀mí rẹ̀ má ṣe gùn;+Kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.+   Kí àwọn ọmọ* rẹ̀ di aláìníbaba,Kí ìyàwó rẹ̀ sì di opó. 10  Kí àwọn ọmọ* rẹ̀ máa tọrọ nǹkan kiri,Kí wọ́n sì máa jáde látinú ilé wọn tó ti di ahoro lọ wá oúnjẹ. 11  Kí ẹni tó jẹ ní gbèsè gbẹ́sẹ̀ lé* gbogbo ohun tó ní,Kí àwọn àjèjì sì kó ohun ìní rẹ̀. 12  Kí ẹnikẹ́ni má ṣe nawọ́ oore* sí i,Kí ẹnikẹ́ni má sì ṣojú rere sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò ní bàbá. 13  Kí àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ pa rẹ́;+Kí orúkọ wọn pa rẹ́ kí ìran tó ń bọ̀ tó dé. 14  Kí Jèhófà rántí àṣìṣe àwọn baba ńlá rẹ̀,+Kí ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ má sì pa rẹ́. 15  Kí Jèhófà máa rántí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe;Kí ó sì pa ìrántí wọn rẹ́ kúrò ní ayé.+ 16  Nítorí kò rántí ṣe oore,*+Àmọ́, ó ń lé ẹni tí ìyà ń jẹ+ àti aláìní pẹ̀lú ẹni tó ní ọgbẹ́ ọkànLáti pa wọ́n.+ 17  Ó fẹ́ràn kó máa gégùn-ún, ohun tó sì dà lé e lórí nìyẹn;Kì í fẹ́ súre, torí náà, kò rí ìbùkún kankan gbà. 18  Ó gbé ègún wọ̀ bí aṣọ. Ó dà sínú ara rẹ̀ bí omi,Ó sì wọnú egungun rẹ̀ bí òróró. 19  Kí ègún wé mọ́ ọn bí aṣọ tó ń wọ̀+Àti bí àmùrè tó ń dè nígbà gbogbo. 20  Ohun tí Jèhófà máa san fún ẹni tó ń ta kò mí nìyí+Àti fún àwọn tó ń sọ̀rọ̀ burúkú sí mi.* 21  Àmọ́ ìwọ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,Gbèjà mi nítorí orúkọ rẹ.+ Gbà mí sílẹ̀, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára.+ 22  Mi ò lè ṣe nǹkan kan, mo jẹ́ aláìní,+Ọkàn mi sì ti gbọgbẹ́.+ 23  Mò ń kọjá lọ bí òjìji tó ń pa rẹ́ lọ;Wọ́n ti gbọ̀n mí dà nù bí eéṣú. 24  Àwọn eékún mi ti yẹ̀ nítorí ààwẹ̀ gbígbà;Mo ti rù, mo sì ń kú lọ.* 25  Mo ti di ohun tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́.+ Tí wọ́n bá rí mi, ṣe ni wọ́n ń mi orí.+ 26  Ràn mí lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi;Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ gbà mí. 27  Kí wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ló ṣe èyí;Pé ìwọ, Jèhófà, ló ṣe é. 28  Kí wọ́n gégùn-ún, àmọ́ ṣe ni kí o súre fún mi. Tí wọ́n bá dìde sí mi, jẹ́ kí ojú tì wọ́n,Àmọ́ kí ìránṣẹ́ rẹ máa yọ̀. 29  Kí ẹ̀tẹ́ bo àwọn tó ń ta kò mí;Kí wọ́n gbé ìtìjú wọ̀ bí aṣọ.*+ 30  Ẹnu mi á máa yin Jèhófà gidigidi;Màá máa yìn ín níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn.+ 31  Nítorí á dúró ní ọwọ́ ọ̀tún aláìníLáti gbà á lọ́wọ́ àwọn tó ń dá a* lẹ́bi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “afinisùn.”
Tàbí “kí wọ́n pè é ní ẹni burúkú.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Tàbí “ẹni tó ń gba èlé gọbọi dẹ pańpẹ́ mú.”
Tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”
Tàbí “ìran àtẹ̀lé.”
Tàbí “fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Ní Héb., “Ara mi ti rù, láìní ọ̀rá (òróró).”
Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀.”