Sáàmù 26:1-12
Ti Dáfídì.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, nítorí mo ti rìn nínú ìwà títọ́ mi;+Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé láìmikàn.+
2 Yẹ̀ mí wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò;Yọ́ èrò inú mi* àti ọkàn mi mọ́.+
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa ń wà níwájú mi nígbà gbogbo,Mo sì ń rìn nínú òtítọ́ rẹ.+
4 Èmi kì í bá àwọn ẹlẹ́tàn kẹ́gbẹ́,*+Mo sì máa ń yẹra fún àwọn tó ń fi ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.*
5 Mo kórìíra àwùjọ àwọn aṣebi,+Mi ò sì jẹ́ bá àwọn ẹni burúkú kẹ́gbẹ́.*+
6 Màá jẹ́ kí ọwọ́ mi mọ́,Màá sì rìn yí ká pẹpẹ rẹ, Jèhófà,
7 Láti mú kí a gbọ́ ohùn ọpẹ́+Àti láti kéde gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.
8 Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ilé tí ò ń gbé,+Ibi tí ògo rẹ wà.+
9 Má ṣe gbá mi* dà nù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀+Má sì gba ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn oníwà ipá,*
10 Àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìwà àìnítìjú,Tí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì kún ọwọ́ ọ̀tún wọn.
11 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.
Gbà mí sílẹ̀,* kí o sì ṣojú rere sí mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú;+Nínú ìjọ ńlá,* èmi yóò yin Jèhófà.+

