Sáàmù 87:1-7
-
Síónì, ìlú Ọlọ́run tòótọ́
-
Àwọn tí a bí ní Síónì (4-6)
-
Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin atunilára. Orin.
87 Ìpìlẹ̀ ìlú rẹ̀ wà lórí àwọn òkè mímọ́.+
2 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè Síónì +Ju gbogbo àwọn àgọ́ Jékọ́bù lọ.
3 Àwọn ohun ológo ni wọ́n ń sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú Ọlọ́run tòótọ́.+ (Sélà)
4 Màá ka Ráhábù+ àti Bábílónì mọ́ àwọn tó mọ̀ mí;*Filísíà àti Tírè nìyí, pẹ̀lú Kúṣì.
Àwọn èèyàn á sọ pé: “Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.”
5 Wọ́n á sọ nípa Síónì pé:
“Inú rẹ̀ ni a ti bí wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.”
Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
6 Jèhófà yóò kéde nígbà tó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èèyàn náà pé:
“Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.” (Sélà)
7 Àwọn akọrin+ àti àwọn tó ń jó ijó àjóyípo+ á sọ pé:
“Gbogbo ìsun omi mi wà nínú rẹ.”*+

