Sáàmù 143:1-12
Orin Dáfídì.
143 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.
Dá mi lóhùn nínú òtítọ́ rẹ àti òdodo rẹ.
2 Má ṣe bá ìránṣẹ́ rẹ ṣẹjọ́,Nítorí kò sí alààyè kankan tó lè jẹ́ olódodo níwájú rẹ.+
3 Nítorí ọ̀tá ń lépa mi;*Ó ti tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀.
Ó ti mú kí n máa gbé inú òkùnkùn bí àwọn tó ti kú tipẹ́tipẹ́.
4 Àárẹ̀ mú ẹ̀mí mi;*+Ọkàn mi kú tipiri nínú mi.+
5 Mo rántí àwọn ọjọ́ àtijọ́;Mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;+Ó ń yá mi lára láti máa ronú lórí* iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
6 Mo tẹ́ ọwọ́ mi sí ọ;Mò* ń wá ọ bí ilẹ̀ tó gbẹ táútáú ṣe ń wá òjò.+ (Sélà)
7 Jọ̀ọ́ Jèhófà, tètè dá mi lóhùn;+Agbára* mi ti tán.+
Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi,+Kí n má bàa dà bí àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*+
8 Ní àárọ̀, jẹ́ kí n gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.
Jẹ́ kí n mọ ọ̀nà tó yẹ kí n máa rìn,+Nítorí ìwọ ni mo yíjú sí.*
9 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Jèhófà.
Ààbò rẹ ni mò ń wá.+
10 Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,+Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi.
Ẹ̀mí rẹ dára;Kí ó máa darí mi ní ilẹ̀ tó tẹ́jú.*
11 Jèhófà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n máa wà láàyè nítorí orúkọ rẹ.
Gbà mí* nínú wàhálà nítorí òdodo rẹ.+
12 Pa àwọn ọ̀tá mi rẹ́*+ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;Pa gbogbo àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ mi* run,+Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni mí.+

