Sáàmù 148:1-14

  • Kí gbogbo ẹ̀dá máa yin Jèhófà

    • “Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀” (2)

    • ‘Ẹ yìn ín, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀’ (3)

    • Kí àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn arúgbó máa yin Ọlọ́run (12, 13)

148  Ẹ yin Jáà!* Ẹ yin Jèhófà láti ọ̀run;+Ẹ yìn ín ní àwọn ibi gíga.  Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀.+ Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.+  Ẹ yìn ín, oòrùn àti òṣùpá. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tó ń tàn.+  Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọ̀run gíga jù lọ*Àti ẹ̀yin omi tó wà lókè àwọn ọ̀run.  Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà,Nítorí ó pàṣẹ, a sì dá wọn.+  Ó fìdí wọn múlẹ̀ kí wọ́n lè wà títí láé àti láéláé;+Ó pa àṣẹ tí kò ní kọjá lọ.+  Ẹ yin Jèhófà láti ayé,Ẹ̀yin ẹ̀dá ńlá inú òkun àti gbogbo ẹ̀yin ibú omi,  Ẹ̀yin mànàmáná àti yìnyín ńlá, yìnyín kéékèèké àti ojú ọ̀run tó ṣú bolẹ̀,Ìwọ ìjì líle, tó ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,+  Ẹ̀yin òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀yin òkè kéékèèké,+Ẹ̀yin igi eléso àti gbogbo ẹ̀yin igi kédárì,+ 10  Ẹ̀yin ẹranko igbó+ àti gbogbo ẹ̀yin ẹran ọ̀sìn,Ẹ̀yin ohun tó ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́, 11  Ẹ̀yin ọba ayé àti gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,Ẹ̀yin olórí àti gbogbo ẹ̀yin onídàájọ́ ayé,+ 12  Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin,*Ẹ̀yin àgbà ọkùnrin àti ẹ̀yin ọ̀dọ́.* 13  Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà,Nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ló ga kọjá ibi tó ṣeé dé.+ Iyì rẹ̀ ga ju ayé àti ọ̀run lọ.+ 14  Yóò gbé agbára* àwọn èèyàn rẹ̀ ga,Ìyìn gbogbo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,Ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tó sún mọ́ ọn. Ẹ yin Jáà!*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Ní Héb., “ọ̀run àwọn ọ̀run.”
Ní Héb., “wúńdíá.”
Tàbí “arúgbó àti ọ̀dọ́.”
Ní Héb., “ìwo.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.