Sáàmù 19:1-14

  • Òfin Ọlọ́run àti àwọn ohun tó dá ń jẹ́rìí

    • “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run” (1)

    • Òfin pípé Ọlọ́run ń sọ agbára dọ̀tun (7

    • “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mi ò mọ̀ nípa rẹ̀” (12)

Sí olùdarí. Orin Dáfídì. 19  Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run;+Ojú ọ̀run* sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+   Láti ọjọ́ dé ọjọ́, ọ̀rọ̀ wọn ń tú jáde,Láti òru dé òru, wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn.   Wọn kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀;A kò gbọ́ ohùn wọn.   Síbẹ̀ ohùn wọn ti dún* jáde lọ sí gbogbo ayé,Iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́ sì ti dé ìkángun ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.*+ Ọlọ́run ti pàgọ́ fún oòrùn sí ọ̀run;   Ó dà bí ọkọ ìyàwó tó ń jáde bọ̀ látinú yàrá ìgbéyàwó;Inú rẹ̀ ń dùn bí alágbára ọkùnrin tó ń sáré ní ipa ọ̀nà rẹ̀.   Ó máa ń jáde láti ìkángun kan ọ̀run,Á sì yí lọ dé ìkángun kejì;+Kò sí nǹkan kan tó fara pa mọ́ kúrò nínú ooru rẹ̀.   Òfin Jèhófà pé,+ ó ń sọ agbára dọ̀tun.*+ Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,+ ó ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.+   Àwọn ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ òdodo, wọ́n ń mú ọkàn yọ̀;+Àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.+   Ìbẹ̀rù Jèhófà+ mọ́, ó wà títí láé. Àwọn ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́, òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.+ 10  Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà,Ju ọ̀pọ̀ wúrà tó dáa,*+Wọ́n sì dùn ju oyin lọ,+ oyin inú afárá. 11  A ti fi wọ́n kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ;+Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.+ 12  Ta ló lè mọ àwọn àṣìṣe?+ Wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mi ò mọ̀ nípa rẹ̀. 13  Má ṣe jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ hùwà ògbójú;+Má ṣe jẹ́ kí ó jọba lé mi lórí.+ Nígbà náà, màá pé pérépéré,+Ọwọ́ mi á sì mọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.* 14  Kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn miMáa múnú rẹ dùn,+ Jèhófà, Àpáta mi+ àti Olùràpadà mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Òfúrufú.”
Tàbí kó jẹ́, “okùn ìdíwọ̀n wọn ti.”
Tàbí “ilẹ̀ tó ń mú èso jáde.”
Tàbí “mú ọkàn sọ jí (pa dà wá).”
Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”
Tàbí “ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.”