Sáàmù 90:1-17

  • Ọlọ́run ayérayé àti èèyàn ẹlẹ́mìí kúkúrú

    • Ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí àná (4)

    • Ọjọ́ ayé èèyàn jẹ́ 70 sí 80 ọdún (10)

    • “Kọ́ wa bí a ó ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa” (12)

Àdúrà Mósè, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.+ 90  Jèhófà, ìwọ ni ibùgbé*+ wa láti ìran dé ìran.   Kí a tó bí àwọn òkèTàbí kí o tó dá ayé àti ilẹ̀ tó ń méso jáde,*+Láti ayérayé dé ayérayé,* ìwọ ni Ọlọ́run.+   O mú kí ẹni kíkú pa dà sínú erùpẹ̀;O sọ pé: “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”+   Nítorí bí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá, á dà bí àná lójú rẹ,+Bí ìṣọ́ kan ní òru.   O gbá wọn lọ;+ wọ́n dà bí oorun lásán;Ní àárọ̀, wọ́n dà bíi koríko tó yọ.+   Ní àárọ̀, ó yọ ìtànná, ó sì dọ̀tun,Àmọ́ ní ìrọ̀lẹ́, ó rọ, ó sì gbẹ dà nù.+   Nítorí pé ìbínú rẹ ti pa wá run,+Ìrunú rẹ sì ti da jìnnìjìnnì bò wá.   O gbé àwọn àṣìṣe wa sí iwájú rẹ;*+Ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ tú àwọn àṣírí wa.+   Àwọn ọjọ́ ayé wa* ń dín kù nítorí ìbínú ńlá rẹ;Àwọn ọdún wa ń lọ sí òpin bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.* 10  Àádọ́rin (70) ọdún ni gígùn ọjọ́ ayé wa,Tàbí kó jẹ́ ọgọ́rin (80) ọdún+ tí èèyàn bá lókun tó ṣàrà ọ̀tọ̀.* Síbẹ̀, wàhálà àti ìbànújẹ́ ló kún inú wọn;Wọ́n á kọjá lọ kíákíá, a ó sì fò lọ.+ 11  Ta ló lè fòye mọ bí ìbínú rẹ ṣe le tó? Bí ìbínú ńlá rẹ ṣe pọ̀ ni ẹ̀rù tó yẹ ọ́ ṣe pọ̀.+ 12  Kọ́ wa bí a ó ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa+Ká lè ní ọkàn ọgbọ́n. 13  Pa dà, Jèhófà!+ Ìgbà wo ni èyí máa dópin?+ Ṣàánú àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+ 14  Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ tẹ́ wa lọ́rùn ní àárọ̀,Ká lè máa kígbe ayọ̀, kí inú wa sì máa dùn+ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. 15  Jẹ́ kí ọjọ́ tí inú wa yóò fi máa dùn pọ̀ bí iye ọjọ́ tí o fi fìyà jẹ wá,+Kí ó sì pọ̀ bí àwọn ọdún tí àjálù fi bá wa.+ 16  Kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ rí iṣẹ́ rẹ,Kí àwọn ọmọ wọn sì rí ọlá ńlá rẹ.+ 17  Kí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run wa wà lára wa;Mú kí iṣẹ́ ọwọ́ wa yọrí sí rere.* Bẹ́ẹ̀ ni, mú kí iṣẹ́ ọwọ́ wa yọrí sí rere.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “ibi ààbò.”
Tàbí “kí o tó bí ayé àti ilẹ̀ tó ń méso jáde nínú ìrora ìbímọ.”
Tàbí “Láti ayé àìnípẹ̀kun títí dé ayé àìnípẹ̀kun.”
Tàbí “O mọ àwọn àṣìṣe wa.”
Tàbí “Ẹ̀mí wa.”
Tàbí “èémí àmíkanlẹ̀.”
Tàbí “nítorí agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”
Tàbí “fìdí múlẹ̀.”
Tàbí “fìdí múlẹ̀.”