Sáàmù 46:1-11

  • “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa”

    • Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run (8)

    • Ọlọ́run fòpin sí ogun ní gbogbo ayé (9)

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Lọ́nà ti Álámótì.* Orin. 46  Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa,+Ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.+   Ìdí nìyẹn tí a kò fi ní bẹ̀rù, bí ayé tilẹ̀ ń mì tìtì,Bí àwọn òkè tilẹ̀ ń ṣubú sínú ibú òkun,+   Bí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń pariwo, tó sì ń ru sókè,*+Bí àwọn òkè tilẹ̀ ń mì jìgìjìgì nítorí ìrugùdù rẹ̀. (Sélà)   Odò kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ ń mú kí ìlú Ọlọ́run máa yọ̀,+Àgọ́ ìjọsìn mímọ́ títóbi ti Ẹni Gíga Jù Lọ.   Ọlọ́run wà nínú ìlú náà;+ kò ṣeé bì ṣubú. Ọlọ́run á ràn án lọ́wọ́ tí ilẹ̀ bá mọ́.+   Àwọn orílẹ̀-èdè wà nínú rúkèrúdò, àwọn ìjọba ń ṣubú;Ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ayé sì yọ́.+   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+Ọlọ́run Jékọ́bù ni ibi ààbò wa.* (Sélà)   Ẹ wá wo àwọn iṣẹ́ Jèhófà,Bí ó ṣe gbé àwọn ohun àgbàyanu ṣe ní ayé.   Ó ń fòpin sí ogun kárí ayé.+ Ó ṣẹ́ ọrun, ó sì kán ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́;Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun* nínú iná. 10  “Ẹ túúbá, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run. A ó gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+A ó gbé mi ga ní ayé.”+ 11  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ ibi ààbò fún wa.+ (Sélà)

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “yọ ìfófòó.”
Tàbí “ibi gíga wa tó láàbò.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn apata.”